A Dáhùn Gbogbo Ìbéèrè Rẹ̀
Ọkùnrin kan tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn sí ní Íńdíà rí i pé ohun tí wọ́n ń fi kọ́ni yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí wọ́n ti kọ́ òun ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ó bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa èyí, ó sì tilẹ̀ kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn ní Íńdíà láti béèrè àwọn ìbéèrè.
Lẹ́yìn náà, lọ́jọ́ kan, ọkùnrin náà kọ lẹ́tà kan tí ó bẹ̀rẹ̀ báyìí pé: “Ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n ní Lonavla”—ibi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí wà ní Íńdíà. Ó ṣàlàyé pé: “Gbogbo iyè méjì àti ìbéèrè mi ni ẹ ti dáhùn láìjanpata nínú ìwé ìròyìn Jí!, May 8, 1995, lábẹ́ àkórí ọ̀rọ̀ náà, ‘Ìwọ Ha Ti Ṣe Kàyéfì Rí Bí?’ Mo ti rí ẹ̀rí pátápátá pé, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní òtítọ́.”
Àpilẹ̀kọ inú Jí! yẹn ti dáhùn àwọn ìbéèrè bí èyí tí ó tẹ̀ lé e yìí: “Ìsìn tòótọ́ yóò ha gbìyànjú láti fi orúkọ Ọlọrun tí a ṣí payá pamọ́ tàbí kí ó fi òmíràn rọ́pò rẹ̀ bí?” “Irú ìwà wo ni ìsìn tòótọ́ níláti mú jáde gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀?” “Ǹjẹ́ ìjọsìn tí Ọlọrun fọ́wọ́sí yóò fàyè gba ìkópa nínú ogun àti ìpànìyàn ẹ̀yà ìran tàbí ẹlẹ́yàmẹ̀yà bí?”
A ní ìdánilójú pé Jí! lè ran ìwọ pẹ̀lú lọ́wọ́ nínú wíwá ẹ̀kọ́ Bíbélì kiri. Bí o bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè gba ẹ̀dà kan tàbí tí o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá sí ilé rẹ láti jíròrò Bíbélì pẹ̀lú rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.