Ó Ń Sọ Ìrètí Dọ̀tun
Èrò ọkùnrin kan tí ó gba ẹ̀dà ìwé àṣàrò kúkúrú olójú ewé mẹ́rin tí a pè ní Ìròyìn Ìjọba nìyẹn. A fún un ní àkọlé náà, “Èéṣe Tí Ìgbésí-Ayé Fi Kún fún Ìṣòro Tóbẹ́ẹ̀?” Wọ́n tẹ lẹ́tà tí ọkùnrin náà kọ nípa rẹ̀ jáde nínú ìwé agbéròyìnjáde El Tiempo, ti Bogotá, Colombia. Ó kọ̀wé pé:
“Ní àkókò yí tí ó jọ pé gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ń mú ìwà ipá àti ìwà ìbàjẹ́ lọ́wọ́, tí a rò pé ìrètí wa ń tán lọ, ó kù sọ́wọ́ wa láti wá ìwọ̀n ipò tẹ̀mí púpọ̀ tó tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti pa ìgbàgbọ́ wa mọ́. Àkópọ̀ ọ̀rọ̀ inú ẹ̀dà tí wọ́n fún mi wí pé:
“‘Bíbélì ṣí i payá pé Ọlọ́run yóò dásí àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn nípasẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀ ọ̀run ní ọwọ́ Jésù Kristi. Ìjọba yìí yóò fọ́ gbogbo àwọn ìṣàkóso oníwà ìbàjẹ́ túútúú kúrò lórí pílánẹ́ẹ̀tì yí. Àwọn kan yóò ha la òpin ayé yìí já bí? Ibo ni àwọn olùlàájá wọ̀nyí yóò gbé títí láé? Olódodo ni yóò jogún ayé. Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, ikú kì yóò sí mọ́. Kì yóò sí ìwà ọ̀daràn, ipò òṣì, ebi, àìsàn, igbe ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ikú mọ́. Àwọn òkú yóò tún pa dà wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i, ilẹ̀ ayé fúnra rẹ̀ ni a óò sì sọ di párádísè kan ní ti gidi.’”
Ìdùnnú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n fẹ́ láti ní ìmọ̀ Bíbélì sí i. Bí o bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni síwájú sí i, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.