Ó Mú Kí Wọ́n Wàásù
Ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pọ̀ ní Khabarovsk, ìlú ńlá kan tí àwọn ènìyàn ibẹ̀ jẹ́ nǹkan bí 700,000 ní Ìkángun Ìlà Oòrùn Rọ́ṣíà. Àwọn obìnrin méjì tí ń gbé abúlé kan tí kò jìnnà síbẹ̀ gba ẹ̀dà ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Khabarovsk kò lè lọ bẹ̀ wọ́n wò ní abúlé wọn.
Nítorí náà, àwọn obìnrin náà lo ọ̀nà dídára jù lọ tí wọ́n mọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ nínú ìwé náà, ní lílo Bíbélì. Lẹ́yìn tí wọ́n parí rẹ̀, wọ́n pinnu pé ó ṣe pàtàkì láti sọ ohun tí àwọn ti kọ́ fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ti ṣe gẹ́lẹ́.—Mátíù 10:7; Ìṣe 20:20.
Àwọn obìnrin náà bá ọkùnrin kan pàdé lẹ́nu ilẹ̀kùn àkọ́kọ́ tí wọ́n lọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀. Láìpẹ́, ìyàwó ọkùnrin náà àti ọmọbìnrin rẹ̀ dara pọ̀ nínú ìjíròrò Bíbélì déédéé. Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí àwọn márààrún bá Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn pàdé, wọ́n ṣèrìbọmi. Àwọn obìnrin náà tí wọ́n lo ìdánúṣe láti ké sí àwọn mìíràn jẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún báyìí.
Kíka ìwé náà, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, lè mú kí ìwọ pẹ̀lú ṣàjọpín àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Bí o bá fẹ́ ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè gba ẹ̀dà kan tàbí bí o bá fẹ́ kí ẹnì kan bẹ̀ ọ́ wò láti bá ọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.