April 11, 1998—Ọjọ́ Tí A Ní Láti Rántí
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó pín búrẹ́dì aláìwú kan àti ife wáìnì kan fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó ní kí wọ́n jẹ, kí wọ́n sì mu. Ó tún wí fún wọn pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.
Lọ́dún yìí, àyájọ́ àjọ̀dún yìí bọ́ sí Saturday, April 11, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé yóò pé jọ pọ̀ ní alẹ́ àkànṣe yìí láti ṣàjọ̀dún Ìṣe Ìrántí yìí lọ́nà tí Jésù pàṣẹ rẹ̀. Tọ̀yàyàtọ̀yàyà ni a ké sí ọ láti dara pọ̀ mọ́ wa gẹ́gẹ́ bí òǹwòran. Jọ̀wọ́ wádìí àkókò àti ibi ìpàdé pàtó lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n wà ládùúgbò rẹ.