Akọ̀ròyìn Kan Mọyì Jí!
Àwọn ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn tí ó wà nísàlẹ̀ yìí fara hàn nínú ìwé ìròyìn High Country News ti October 13, 1997, tí wọ́n tẹ̀ jáde ní Paonia, Colorado, U.S.A.
“Ó ṣeé ṣe kí àjọ Greenpeace [àjọ kan tí ń rí sí ọ̀ràn àyíká lágbàáyé] máà máa lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà mọ́, ṣùgbọ́n àwùjọ mìíràn kan ń bá ọ̀nà ìjíròrò rẹ̀ ọlọ́jọ́-pípẹ́ nìṣó, ó ń tẹnu mọ́ àwọn ọ̀ràn àyíká lọ́pọ̀ ìgbà. Ó ń pín àràádọ́ta ọ̀kẹ́ [mílíọ̀nù 19 nínú ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan] ẹ̀dà ìwé rẹ̀ ní nǹkan bí 60 [81 ní gidi] èdè, títí kan àwọn èdè Pidgin, Hiligaynon àti Zulu. Ìtẹ̀jáde July 8 [1997] béèrè ní ẹ̀yìn ìwé rẹ̀ pé: ‘Ta Ni Yóò Dáàbò Bo Àwọn Ẹranko Wa?,’ ó sì ní àpilẹ̀kọ kan nínú tó sọ nípa bí àkúrun ṣe ń yára ṣẹlẹ̀ tó (mẹ́ta ní wákàtí kọ̀ọ̀kan), ‘ìlera àdánidá pílánẹ́ẹ̀tì náà,’ àti mímọ̀ọ́mọ̀ ba àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn jẹ́ . . . Ìtẹ̀jáde Aug. 22, 1997, jíròrò ‘Ìṣòro Omi: Wàhálà Tó Kárí Ayé,’ àti ipa tí ìbúrẹ́kẹ iye ènìyàn, ìbàyíkájẹ́ òun àìfararọ àgbáyé ń ní lórí bí a ṣe ń lo àwọn odò . . . Nígbà tí àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí máa ń dá lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, tí wọ́n sì ń kárí apá púpọ̀, ìparí ọ̀pọ̀ lára wọn kì í ṣe ti ìgbẹnusọ fún ààbò àti ìmúsunwọ̀n àyíká àdánidá tí gbogbo ènìyàn mọ̀. Wọ́n ń sọ pé bí o bá fẹ́ láti ṣàjọpín ìmúbọ̀sípò ilẹ̀ ayé, ‘Nígbà náà, jọ̀wọ́ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí o ṣe nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.’
“Àwùjọ náà ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìtẹ̀jáde náà sì ni Jí! Bí wọn kì í bá wá sẹ́nu ọ̀nà rẹ, kàn sí Watchtower Bible and Tract Society of New York Inc., 25 Columbia Heights, Brooklyn, NY 11201-2483.”
Kò lè ṣeé ṣe fún wa láti sọ ọ́ lọ́nà tó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, àfi kí a fi kún un pé, “tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó sún mọ́ ọ jù lọ nínú àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5 ìwé ìròyìn Jí!”