Àwọn Ìtumọ̀ Bíbélì Ìjímìjí Ń wà Nìṣó
Láàárín 1994 àti 1995, Ibi Ìkówèésí Ilẹ̀ Britain pàtẹ ẹ̀dà ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí William Tyndale ṣe lódindi ní 1526, tí a tẹ̀ nígbà tí ó wà ní ìgbèkùn ní Worms, Germany. Kọ́lẹ́ẹ̀jì Onítẹ̀bọmi Bristol ti England ni wọ́n ti ra ìwé yìí ní iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 1,600,000 dọ́là, níwọ̀n bí a ti ronú pé òun ni ẹ̀dà kan ṣoṣo tí ó ṣì wà lódindi—bíṣọ́ọ̀bù London ló ru àwọn ènìyàn sókè láti sun 3,000 tán-n-tán tàbí iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ṣe fàyàwọ́ rẹ̀ wọ England. Bí ó ti wù kí ó rí, a ti rí ẹ̀dà mìíràn tí ó jẹ́ odindi nínú ìtẹ̀jáde yìí, ní ibi ìkówèésí kan ní Stuttgart, Germany. Nítorí pé wọ́n ṣi orúkọ tẹ̀ sára rẹ̀, wọ́n sì gbójú fò ó fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, bí wọn ṣe ṣe ìdìpọ̀ rẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún ló wà, bákan náà sì ni ojú ewé tí wọ́n kọ orúkọ rẹ̀ sí wà bí ó ṣe wà nígbà náà.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Ọ̀gá, Àwọn Ògbógi àti Àwọn Ọ̀mọ̀wé Ilé Ẹ̀kọ́ Hertford, Oxford
© Württ. Landesbibliothek/Fotograf: Joachim Siener