Irúgbìn Amaranth—Oúnjẹ Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Aztec
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ MEXICO
ALEGRÍA, mindinmí-ìndìn aṣaralóore kan tí a túmọ̀ orúkọ rẹ̀ lédè Sípéènì sí “ayọ̀” tàbí “ìdùnnú,” ni a sábà máa ń rí ní àwọn búkà jíjojúnígbèsè ní àwọn ọjà tí wọ́n ti ń ta oúnjẹ ní Mexico. Èso irúgbìn amaranth olódòdó pupa, tí ó máa ń hù ní ilẹ̀ olóoru, ni wọ́n fi ṣe é. Ògidì oyin ni wọ́n fi ṣe mindinmí-ìndìn náà, wọ́n sì máa ń fi àsálà, kóró èso ahóyaya, àti èso àjàrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. A tún lè lọ èso irúgbìn amaranth di oúnjẹ oníhóró tàbí ìyẹ̀fun, tí a ń fi ṣe búrẹ́dì àti kéèkì.
Àwọn Aztec ń fi ìyẹ̀fun irúgbìn amaranth ṣe kéèkì tortilla, wọ́n sì ń sè é mọ́ ẹran lílọ̀ tamale. Ní àfikún, irúgbìn amaranth ń kó ipa pàtàkì kan nínú àwọn ààtò ìsìn wọn. Ìwé agbéròyìnjáde The News ti Ìlú Ńlá Mexico sọ pé: “Nínú ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ààtò ìsìn tí àwọn Aztec ń ṣe, wọn á ki búrẹ́dì tí wọ́n fi irúgbìn amaranth ṣe bọnú ẹ̀jẹ̀ ọ̀kan lára àwọn ọ̀tá wọn tí wọ́n mú, tí wọ́n sì [pa], wọ́n á sì jẹ ẹ́.” Àṣà mìíràn ni ti pípo èso amaranth lílọ̀ pọ̀ mọ́ àgbàdo àti oyin, wọ́n óò sì fi àpòpọ̀ náà ṣe àwọn ère tàbí òrìṣà kéékèèké. Àwọn ère wọ̀nyí ni wọ́n máa ń jẹ lẹ́yìn náà nígbà ààtò ìsìn kan tí ó jọ ti Jíjẹ Ara Olúwa ní ìjọ Kátólíìkì.
Àwọn àṣà méjèèjì yìí bí aṣẹ́gun ará Sípéènì náà, Hernán Cortés, nínú, èyí sì mú kí ó fòfin de gbígbin irúgbìn amaranth àti jíjẹ ẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbójúgbóyà tẹ òfin rẹ̀ lójú ni wọ́n ń pa tàbí kí wọ́n gé ọwọ́ tí ó rúfin náà. Èyí ló mú kí ọ̀kan lára àwọn irúgbìn tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ní Mexico nígbà náà fẹ́rẹ̀ẹ́ pòórá.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, irúgbìn amaranth ṣì ń wà nìṣó, lọ́nà kan ṣáá, ó ṣí lọ sí Himalayas láti Àáríngbùngbùn Amẹ́ríkà. Láàárín ọ̀rúndún tí ó kọjá, ó ti di lájorí oúnjẹ láàárín àwọn ẹ̀yà tí ń gbé àárín àwọn òkè ńlá ní China, Íńdíà, Nepal, Pakistan, àti Tibet.
Ní Mexico, àwọn olùwádìí ti ń gbìyànjú láìpẹ́ yìí láti yọ èròjà protein inú èso náà láti fi ṣe wàrà amaranth, ohun mímu tí ìwọ̀n ìṣaralóore rẹ̀ bá ti wàrà màlúù dọ́gba. Ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe ni láti lò ó láti fi kún èròjà inú oúnjẹ àti ohun mímu fún àwọn tí wọn kò lè ra ẹyin, wàrà, ẹja, tàbí ẹran màlúù.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irúgbìn amaranth ti la ọ̀pọ̀ ìṣòro kọjá, ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣì ń gbádùn oúnjẹ aṣaralóore, tí ó wúlò lọ́nà púpọ̀ yìí lónìí.