Báwo ni Tẹlifíṣọ̀n Ṣe Léwu Tó?
Ní December 18, 1997, àwọn àkọlé ìwé ìròyìn sọ pé àwòrán àfiṣènìyàn kan lórí tẹlifíṣọ̀n sọ ọ̀pọ̀ ènìyàn daláìsàn ní Tokyo, Japan. Wọ́n kó ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn lọ sílé ìwòsàn. Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Àwọn ọmọ kan bi ẹ̀jẹ̀, gìrì mú àwọn mìíràn tàbí wọ́n dá kú. Àwọn dókítà àti àwọn afìṣemọ̀rònú kìlọ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ìránnilétí nípa bí àwọn ohun kan tí wọ́n ń ṣe nínú tẹlifíṣọ̀n lóde òní ṣe lè nípa lórí àwọn ọmọdé.”
Ìwé ìròyìn Daily News ti New York sọ pé: “Ìpayà mú Japan lánàá, nígbà tí àwòrán àfiṣènìyàn kan tí ó dà bí ẹbọra lórí tẹlifíṣọ̀n yí ojú rẹ̀ pupa, tí gìrì sì mú ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọdé jákèjádò orílẹ̀-èdè náà.
“A kó iye ọmọdé tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 600 àti àwọn àgbàlagbà mélòó kan lọ sí àwọn iyàrá ìtọ́jú pàjáwìrì lálẹ́ Tuesday lẹ́yìn tí wọ́n ti wo . . . àwòrán àfiṣènìyàn kan lórí tẹlifíṣọ̀n.” Wọ́n gba àwọn kan tí ó ṣòro fún láti mí síbi ìtọ́jú àrà ọ̀tọ̀.
Yukiko Iwasaki, ìyá ọmọ ọlọ́dún mẹ́jọ kan sọ pé: “Àyà mi já nígbà tí ọmọbìnrin mi dákú. Nígbà tí mo lù ú lẹ́yìn ló ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mí.”
Àwọn tí ń gbé ètò orí tẹlifíṣọ̀n jáde fún àwọn ọmọdé kò lè ṣàlàyé bí ọgbọ́n ìfàwòrán-ṣènìyàn tí wọ́n sọ pé àwọn ti lò “ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìgbà” ṣe lè ṣokùnfà irú ìṣẹ̀lẹ̀ eléwu, tó le bẹ́ẹ̀.
Àwọn òbí kan tí wọ́n mọ ipa eléwu tí tẹlifíṣọ̀n wíwò ń ní ti ń fìṣọ́ra bójú tó tẹlifíṣọ̀n wíwò, tàbí kí wọ́n tilẹ̀ palẹ̀ tẹlifíṣọ̀n mọ́ kúrò nínú ilé wọn. Òbí kan ní Allen, Texas, U.S.A., sọ pé kí àwọn tó gbé tẹlifíṣọ̀n kúrò nílé àwọn, àwọn ọmọ òun ń ṣàfihàn “àìlèpọkànpọ̀ fún ìgbà pípẹ́, ìbínú, àìkìí-fọwọ́-sowọ́pọ̀, àti àárẹ̀ gidigidi.” Ó ṣàlàyé síwájú sí i pé: “Lónìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ wa márààrún—tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún 6 sí 17—ló jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí ń ṣe ipò kìíní nínú gbogbo apá ẹ̀kọ́ wọn. Bí a ti palẹ̀ tẹlifíṣọ̀n mọ́ nílé, wọ́n yára nífẹ̀ẹ́ sí onírúurú nǹkan títí kan eré ìdárayá, ìwé kíkà, àwòrán yíyà, lílo kọ̀ǹpútà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
“Ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé kan ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yìn. Ọmọkùnrin mi, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án nígbà náà, tẹ̀ mí láago láti ibi àpèjẹ àṣemọ́jú nílé ọ̀rẹ́ kan pé òun fẹ́ tètè darí wálé . . . Nígbà tí mo lọ gbé e, tí mo sì béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní, ‘Kò dùn. Gbogbo ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe ni kí wọ́n jókòó, kí wọ́n sì máa wo tẹlifíṣọ̀n!’”