ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 9/8 ojú ìwé 29
  • Èé Ṣe Tí Òfin Fi Sọ Pàtó Pé Kí A Dádọ̀dọ́ Lọ́jọ́ Kẹjọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èé Ṣe Tí Òfin Fi Sọ Pàtó Pé Kí A Dádọ̀dọ́ Lọ́jọ́ Kẹjọ?
  • Jí!—1998
Jí!—1998
g98 9/8 ojú ìwé 29

Èé Ṣe Tí Òfin Fi Sọ Pàtó Pé Kí A Dádọ̀dọ́ Lọ́jọ́ Kẹjọ?

Jèhófà kò ṣàlàyé, kò sì pọndandan fún un láti ṣàlàyé. Ohun tó bá ṣe máa ń tọ́ nígbà gbogbo; èrò rẹ̀ ló sì ń dára jù. (2 Sámúẹ́lì 22:31) Bí ó ti wù kí ó rí, ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ènìyàn ti ń rí àwọn ìdí tí ó fi dára láti dádọ̀dọ́ lọ́jọ́ kẹjọ. Ìwọ̀n èròjà amẹ́jẹ̀dì, tí a ń pè ní fitami K, tó yẹ kó wà nínú ẹ̀jẹ̀ kì í sí títí di ọjọ́ karùn-ún sí ìkeje lẹ́yìn tí a bá bímọ. Kìkì ìpín 30 péré nínú ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n èròjà amẹ́jẹ̀dì mìíràn tí ń jẹ́ prothrombin tó yẹ kó wà lára ló ń wà lára ní ọjọ́ kẹta, àmọ́ ní ọjọ́ kẹjọ, ó ti máa ń pọ̀ lára ju ti ìgbàkigbà mìíràn nínú ìgbésí ayé ọmọ lọ—ó máa ń pọ̀ tó ìpín 110 nínú ọgọ́rùn-ún sí iye tó yẹ kó jẹ́. Nítorí náà, títẹ̀lé àwọn ìmọ̀ràn Jèhófà yóò mú kí a yẹra fún ewu títú ẹ̀jẹ̀ dà nù. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà S. I. McMillen ṣe sọ: “Bí a bá ti ìhà àwọn èròjà fitami K àti prothrombin wò ó, ọjọ́ tó dára jù lọ láti dádọ̀dọ́ ni ọjọ́ kẹjọ . . . ọjọ́ tí Ẹlẹ́dàá fitami K yàn.”—None of These Diseases, 1986, ojú ìwé 21.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe nígbà gbogbo, olórí ilé ló sábà máa ń dádọ̀dọ́ ẹni. Bí àkókò ti ń lọ, a bẹ̀rẹ̀ sí lo ẹnì kan tí a yàn, tí a sì dá lẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ yìí. Nígbà tí ó fi di ọ̀rúndún kìíní, ó jọ pé ó ti di àṣà pé kí a sọ ọmọkùnrin lórúkọ nígbà tí a bá dádọ̀dọ́ rẹ̀.—Lúùkù 1:59, 60; 2:21.

Láàárín 40 ọdún tí wọ́n fi rìn nínú aginjù, wọn kò dádọ̀dọ́ àwọn ọmọkùnrin. Nítorí náà, lẹ́yìn tí wọ́n ré Jọ́dánì kọjá, Jóṣúà fi akọ òkúta ṣe ọ̀bẹ, ó sì dádọ̀dọ́ àwọn ọkùnrin ní Gílígálì, Jèhófà sì dáàbò bò wọ́n títí ara wọn fi mókun padà.—Jóṣúà 5:2-9.

A Kò Pàṣẹ Rẹ̀ fún Àwọn Kristẹni. Lẹ́yìn tí Jèhófà ti fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba àwọn Kèfèrí sínú ìjọ Kristẹni, tí ọ̀pọ̀ ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè sì ń dáhùn sí ìwàásù ìhìn rere náà, ó di dandan fún ẹgbẹ́ olùṣàkóso tó wà ní Jerúsálẹ́mù láti ṣe ìpinnu lórí ìbéèrè náà pé, Ǹjẹ́ ó pọndandan fún àwọn Kèfèrí tó di Kristẹni láti dádọ̀dọ́? Ibi tí wọ́n forí ọ̀rọ̀ náà tì sí ni pé: Dídádọ̀dọ́ kò sí lára àwọn “nǹkan pípọndandan” fún àwọn Kèfèrí àti àwọn Júù.—Ìṣe 15:6-29.

Pọ́ọ̀lù dádọ̀dọ́ Tímótì láìpẹ́ lẹ́yìn tí àṣẹ náà jáde, kì í ṣe bí ọ̀ràn ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n láti dènà ẹ̀tanú àwọn Júù tí wọ́n ń lọ wàásù fún. (Ìṣe 16:1-3; 1 Kọ́ríńtì 9:20) Àpọ́sítélì náà sọ nípa ọ̀ràn náà nínú àwọn lẹ́tà mélòó kan. (Róòmù 2:25-29; Gálátíà 2:11-14; 5:2-6; 6:12-15; Kólósè 2:11; 3:11) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kèfèrí tó di Kristẹni ní ìlú Fílípì pé: “Àwa ni a ní ìdádọ̀dọ́ tòótọ́ [ti ọkàn-àyà], tí a ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run.” (Fílípì 3:3) Ó sì kọ̀wé sí àwọn tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Ìdádọ̀dọ́ kò túmọ̀ sí nǹkan kan, àìdádọ̀dọ́ kò sì túmọ̀ sí nǹkan kan, ṣùgbọ́n pípa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ ṣe bẹ́ẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 7:19.

Ìlò Àfiṣàpẹẹrẹ. A lo “ìdádọ̀dọ́” lọ́nà àfiṣàpẹẹrẹ lọ́pọ̀ ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, a sọ pé, lẹ́yìn gbígbin igi kan ní Ilẹ̀ Ìlérí, “kí ó máa wà ní aláìdádọ̀dọ́” fún ọdún mẹ́ta; a ka èso rẹ̀ sí “adọ̀dọ́” rẹ̀, a kò sì gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́. (Léfítíkù 19:23) Mósè sọ fún Jèhófà pé: “Wò ó! Mo jẹ́ aláìdádọ̀dọ́ ètè, nítorí náà, báwo ni Fáráò yóò ṣe fetí sí mi láé?” (Ẹ́kísódù 6:12, 30) Lọ́nà àfiṣàpẹẹrẹ, àwọn tí ó tọ́ pé kí a sin sí ibì kan náà pẹ̀lú àwọn aláìjámọ́ǹkan tí a pa ni a ń ṣàpèjúwe tẹ̀gàntẹ̀gàn gẹ́gẹ́ bí “àwọn aláìdádọ̀dọ́.”—Ìsíkíẹ́lì 32:18-32.

Ìdádọ̀dọ́ ti ọkàn-àyà jẹ́ ohun tí Ọlọ́run béèrè fún, kódà, ó béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n dádọ̀dọ́ ti ara pàápàá. Mósè sọ fún Ísírẹ́lì pé: “Kí ẹ sì dá adọ̀dọ́ ọkàn-àyà yín, kí ẹ má sì tún mú ọrùn yín le mọ́.” “Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì dádọ̀dọ́ ọkàn-àyà rẹ, àti ọkàn-àyà àwọn ọmọ rẹ, kí o lè fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ nítorí ìwàláàyè rẹ.” (Diutarónómì 10:16; 30:6) Jeremáyà rán orílẹ̀-èdè oníwà wíwọ́ yẹn létí ohun kan náà ní àkókò tirẹ̀. (Jeremáyà 4:4) ‘Ìdádọ̀dọ́ ti ọkàn-àyà’ túmọ̀ sí kíkó ohunkóhun tó wà nínú ìrònú ẹni, ìfẹ́ni ẹni, tàbí ìsúnniṣe ẹni, tí kò ṣètẹ́wọ́gbà tàbí tí kò mọ́ lójú Jèhófà, tí ó sì ń mú kí ọkàn yigbì, dà nù. Lọ́nà kan náà, a sọ̀rọ̀ nípa etí tí kò gbọ́ràn pé ó jẹ́ “aláìdádọ̀dọ́.”—Jeremáyà 6:10; Ìṣe 7:51.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́