Kí Ló Ń Sọ Àwọn Ọ̀dọ́langba Di Ìpáǹle?
ṢÉ O ní èrò tó wọ́pọ̀ náà, pé ìdílé tálákà ni àwọn ìpáǹle ọ̀dọ́langba ti ń wá, àti pé, àwọn ọmọ tó bá wá láti ilé “bọ̀rọ̀kìnní” kì í sábà dáràn? Lójú àwọn kan ní Éṣíà, ó jọ pé àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ń ti èrò yẹn lẹ́yìn. Ìwé ìròyìn Asia Magazine sọ pé: “Kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́. Àwọn àkọsílẹ̀ oníṣirò àti àwọn ìròyìn ìwà ọ̀daràn káàkiri ilẹ̀ Éṣíà, tó wà lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá, fi hàn pé, àwọn ọ̀dọ́ tó wá láti ilé àwọn bọ̀rọ̀kìnní ń pọ̀ sí i nídìí olè jíjà, bíba nǹkan jẹ́, jíjoògùnyó, àti ṣíṣe aṣẹ́wó.”
Bí àpẹẹrẹ, ìdajì àwọn ọ̀dọ́langba tí a fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí ìjìyà rẹ gbópọn kàn ní Japan ló wá láti ìdílé kò-là-kò-ṣagbe. Ipò náà jọra ní Bangkok. Adisai Ahapanun, ọ̀gá àgbà Ilé Ẹ̀kọ́ Muhita, sọ pé: “Látijọ́, àìlówó ló ń fa ìwà ọ̀daràn láàárín àwọn ọ̀dọ́langba. Lóde òní, ó lé ní ìdajì nínú àwọn ọ̀dọ́ tó wà níbí, tó jẹ́ pé ìdílé kò-là-kò-ṣagbe ni wọ́n ti wá, láìsí ìṣòro owó.”
Àwọn kan ń sọ pé ipò náà rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé àwọn ìyá ń lọ síbi iṣẹ́, ìkọ̀sílẹ̀ ń pọ̀ sí i, àwọn ènìyàn sì ń fẹ́ ìgbésí ayé ọlọ́pọ̀ ohun ìní. Eddie Jacob, igbákejì olùdarí ibùdó ìmúbọ̀sípò àwọn oníwà àìbẹ́gbẹ́mu kan tó wà fún àwọn ọ̀dọ́langba ní Singapore, wí pé: “Kókó tó ṣe pàtàkì jù ni ipò ìdílé tí kò gún régé—tí àwọn òbí lè ti kọ ara wọn sílẹ̀, tàbí tí òbí ti jẹ́ anìkàntọ́mọ, tàbí tí àwọn òbí méjèèjì ti ń ṣiṣẹ́, tí a sì pa àwọn ọmọ tì. Ilé ni àwọn ọmọ ti ń kọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe lóde.”
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé, àwọn èwe yóò túbọ̀ máa ṣọ̀tẹ̀ ní àkókò wa. (2 Tímótì 3:1, 2) Síbẹ̀, ìwé yẹn kan náà lè kọ́ àwọn ìdílé ní àwọn ohun tí wọ́n nílò láti sún mọ́ra, láìka ipò ìṣúnná wọn sí. Ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì ní láti sọ nítorí pé, “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:16) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Éṣíà—ní gidi, kárí ayé—ń jàǹfààní nínú kí ìdílé máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì papọ̀. Inú wọn yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́, kí o lè ṣe bákan náà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ìwọ lo ni ìpinnu—yíya ìpáǹle tàbí jíjèrè ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run