Ọlọ́run Ha Wà Bí?—Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Kan Fèsì
NÍGBÀ tí Ulrich J. Becker, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ físíìsì ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gbogbo-ǹ-ṣe ti Massachusetts, ń sọ̀rọ̀ nípa wíwà Ọlọ́run, ó sọ pé: “Báwo ni mo ṣe lè wà láìní ẹlẹ́dàá kan? N kò tíì rí ìdáhùn gúnmọ́ kankan sí èyí.”
Èyí ha lòdì sí èrò ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ó ní bí? Ọ̀rọ̀ amúnironú-jinlẹ̀ tí ọ̀jọ̀gbọ́n náà fi fèsì ni pé, “Bí o bá mọ bí irin róbótó kan ṣe ń yí nínú ‘aago’—o lè fòye mọ bí àwọn yòókù ṣe ń yí, àmọ́, o kò ní ẹ̀tọ́ láti pe èyí ní ohun ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì àti pé ó bọ́gbọ́n mu kí ó má ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè nípa ẹni tó lọ́ irin náà pọ̀.”
Lòdì sí èrò àwọn kan, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí a bọ̀wọ̀ fún gidigidi ni kò fọwọ́ rọ́ èrò náà pé Ọlọ́run kan wà sẹ́yìn, ìyẹn ni Olùdarí Ńlá kan tí ó ṣẹ̀dá àgbáálá ayé àti ènìyàn.
Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ méjì sí i lórí kókó yìí. Nígbà tí wọ́n béèrè èrò John E. Fornaess, tí ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìṣirò ní Yunifásítì Princeton, nípa wíwà Ọlọ́run, ó dáhùn pé: “Mo gbà gbọ́ pé Ọlọ́run kan wà àti pé Ọlọ́run ni ó gbé àgbáálá ayé kalẹ̀ látòkè délẹ̀ láti orí egunrín ìpilẹ̀ṣẹ̀ dé orí àwọn ohun abẹ̀mí títí kan ọ̀wọ́ àwọn ìràwọ̀ tí ó díjú jù lọ.”
Henry Margenau, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ físíìsì ní Yunifásítì Yale, sọ pé ó dá òun lójú pé Ọlọ́run ni ó dá àwọn òfin àdánidá, ó fi kún un pé: “Ọlọ́run dá àgbáálá ayé láti inú òfo, ìgbésẹ̀ yìí ni ó sì mú kí àkókò wà.” Ó wá ṣàkíyèsí pé nínú ìwé náà, The Mystery of Life’s Origin, àwọn mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàlàyé pé Ẹlẹ́dàá kan ni àlàyé tí ó ṣeé gbà gbọ́ fún ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìwàláàyè. Ní títi èrò yìí lẹ́yìn, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà náà, Fred Hoyle, sọ pé gbígbàgbọ́ pé sẹ́ẹ̀lì àkọ́kọ́ pilẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ èèṣì dà bí gbígbàgbọ́ pé àfẹ́yíká ìjì kan tí ó gba àárín ibi tí a ń kó àwókù nǹkan sí, tí ó kún fún àwọn ẹ̀yà ara ọkọ̀ òfuurufú Boeing 747, kọjá lè ṣẹ̀dá ọkọ̀ òfuurufú 747 kan.
A lè fi àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, òǹkọ̀wé Bíbélì náà, kún àwọn ìdáhùn wọ̀nyí pé: “Àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.”—Róòmù 1:20.
Dájúdájú, Ọlọ́run wà! Ṣùgbọ́n kí ni ìdí tí ó fi fàyè gba ipò ìbànújẹ́ tí ayé wà? Kí ni ète rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé? Ǹjẹ́ a lè mọ ẹni tí Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́ ní gidi?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
“Bí o bá mọ bí irin róbótó kan ṣe ń yí nínú ‘aago’—o lè fòye mọ bí àwọn yòókù ṣe ń yí, àmọ́, ó . . . bọ́gbọ́n mu kí o má ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè nípa ẹni tó lọ́ irin náà pọ̀”