Ìpinnu Tí O Kò Ní Kábàámọ̀ Rẹ̀
ÀRÀÁDỌ́TA ọ̀kẹ́ ọkùnrin àti obìnrin tí a bí lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì ni wọ́n ti tó ẹni ogójì ọdún báyìí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ọ̀pọ̀ lára wọn ti gbé ṣe láyé tẹ́ wọn lọ́rùn, àwọn kan nímọ̀lára ìjákulẹ̀. Wọ́n ti ṣègbéyàwó, wọ́n ti ṣiṣẹ́, wọ́n ti bímọ, wọ́n ti ní ìdílé, àwọn òbí àwọn kan sì ti kú lójú wọn. Lónìí, bí wọ́n ti ń darúgbó lọ, tí wọ́n ń tóbi sí i, tí eékún wọn sì ti ń di yọ́gẹyọ̀gẹ, àwọn kan nímọ̀lára pé àwọn kò dé ibi tó yẹ kí àwọn dé láyé àwọn. Ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn lè sún wọn béèrè pé, ‘Kí ni ète ìgbésí ayé?’ Bóyá ìwọ pẹ̀lú ti béèrè ìbéèrè yẹn rí.
Láìsí àní-àní, ó ṣe pàtàkì gan-an láti máa ronú nípa ìgbésí ayé rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ríronú ṣáá lórí àwọn ìpinnu tí o ti ṣe sẹ́yìn, tí o kábàámọ̀ lé lórí, lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. Dípò sísọ lọ́kàn ara rẹ pé, ‘Ká ní mo ti . . . ,’ ì bá dára jù kí o fiyè sí àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu tí o ṣì lè ṣe lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀kan lára irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ láti gbé àwọn ìsọfúnni tí ń dáhùn àwọn ìbéèrè nípa ohun tí ìgbésí ayé túmọ̀ sí yẹ̀ wò. Nítorí náà, a ké sí ọ láti ka ìwé Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? Tí o bá pinnu láti tẹ́wọ́ gba ìkésíni wa, o kò ní kábàámọ̀ rẹ̀.
O lè rí ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ìwé pẹlẹbẹ olójú-ewé méjìlélọ́gbọ̀n yìí gbà nípa kíkọ̀wé kún fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tí a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ wẹ́kú lára àwọn tí a tó sí ojú ìwé karùn-ún ìwé ìròyìn yìí.
□ Mo fẹ́ mọ bí mo ṣe lè rí ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? gbà.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.