Ìtẹ̀jáde Tó ní Ète Ìtẹ̀jáde Tó ní Ète
MỌ́NÍJÀ ibi ìkówèésí kan tó jẹ́ ti ìjọba nílùú Prague, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech, lẹ ìsọfúnni olójú ìwé méjì nípa ìníyelórí Jí! sójú pátákó ìsọfúnni tó wà ní ibi ìkówèésí ọ̀hún. Ara ohun tó kọ nìyí:
“Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ni mí o. Alátìlẹ́yìn gbágbáágbá tàbí alátakò gbígbóná janjan sí Watch Tower Society kọ́ ni mí. Síbẹ̀, mo fi taratara dámọ̀ràn kíka ìwé ìròyìn Jí!, tí mo ti ń kà fúngbà díẹ̀ báyìí. Wíwulẹ̀ ka àkọlé rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lóòjọ́ yóò ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an. Àmọ́, kì í ṣe kìkì àkọlé rẹ̀ ṣùgbọ́n ohun náà gan-an tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí jẹ́ àṣepé tó dáa gan-an ní àfikún sí àwọn ìwé ìròyìn ayé . . .
“Èrò tí Jí! ń gbé jáde pegedé. Ó ń kọ àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ táwọn ìwé ìròyìn yòókù kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, nítorí onírúurú ìdí. Ó ń tọ́ka sí àbájáde iṣẹ́ ọwọ́ wa, ó ń kọ́ wa nípa ohun tó ń lọ lágbàáyé . . . Jí! kì í ṣèdájọ́. Ṣe ló kàn ń sọ òtítọ́ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ àti ojú ìwòye àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn, ó máa ń sọ àwọn àǹfààní àti àléébù, ó ń fa ọ̀rọ̀ Bíbélì yọ láti fi ṣàlàyé àwọn ìṣòro òde òní, yóò sì fi ìyókù sílẹ̀ sọ́wọ́ òǹkàwé láti fúnra rẹ̀ ṣèdájọ́. Kò tán síbẹ̀ o, Jí! ń béèrè ìbéèrè—ó sì ń kọ́ àwọn tí ń kà á láti máa béèrè ìbéèrè.”
A ṣàlàyé lójú ìwé 4 nínú ìwé ìròyìn yìí, lábẹ́ ìsọ̀rí náà “Ìdí Tí A Fi Ń Tẹ Jí! Jáde” pé: “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìwé ìròyìn yìí ń gbé ìgbẹ́kẹ̀lé ró nínú ìlérí tí Ẹlẹ́dàá ti ṣe ní ti ayé tuntun kan tí ó kún fún àlàáfíà, tí ó sì jẹ́ aláìléwu, tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ rọ́pò ètò àwọn nǹkan búburú, aláìlófin ti ìsinsìnyí.”
Ìwọ yóò rí i pé a jíròrò ìlérí tí Ọlọ́run ṣe yìí nínú àkòrí méjì tó gbẹ̀yìn ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé méjìlélọ́gbọ̀n náà, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I? Àkòrí méjèèjì yìí ni “Ète Ọlọrun Yoo Ní Imuṣẹ Laipẹ” àti “Walaaye Titilae Ninu Paradise Ori Ilẹ̀-Ayé Kan.” O lè rí ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ìwé pẹlẹbẹ yìí gbà nípa kíkọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù ìsàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tí a kọ sínú fọ́ọ̀mù náà, tàbí kí o fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí táa tò sí ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí mi nípa bí mo ṣe lè rí ìwé pẹlẹbẹ náà, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, gbà. Sọ èdè tí o fẹ́.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.