Ó Rí Ohun Ṣíṣeyebíye Lájàalẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Kan
Lọ́dún tó kọjá, obìnrin kan láti àríwá New York City, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kọ̀wé pé òún rí ohun ṣíṣeyebíye kan. Ọ̀rọ̀ tí obìnrin náà kọ sára àpòòwé tó fi fi lẹ́tà rẹ̀ ránṣẹ́ ni, “Ẹni Yòówù Kó Jẹ́,” nítorí kò darí rẹ̀ sẹ́nì kan pàtó. Ó wá ṣàlàyé nínú lẹ́tà tó kọ náà pé: “Mo rí ìwé kékeré yìí nínú yàrá ìsàlẹ̀ ṣọ́ọ̀ṣì wa, ni mo bá mú un lọ sílé. Àkòrí ìwé náà ni, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.”
Obìnrin náà ṣàlàyé pé: “Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ẹ̀ẹ̀kejì rèé tí mò ń ka ìwé náà, orí mẹ́rin péré ló sì kù kí n parí rẹ̀. Mo gbádùn ìwé náà débi pé, mo ní láti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kà á lẹ́ẹ̀kejì kí n lè lóye gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ pátá. Ohun tí mo rí kọ́ nínú ìwé yìí ju gbogbo ohun tí mo ti kọ́ látọjọ́ tí mo ti ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ. Mo sì tún rí àwọn ohun tí mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ kọ́. Inú mi ì bá dùn ká ní mo lè túbọ̀ rí irú àwọn ìwé kéékèèké bẹ́ẹ̀ sí i.”
Ogún ọdún sẹ́yìn làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ìwé tí obìnrin yìí rí he, ó sì lé ní mílíọ̀nù mọ́kànlélọ́gọ́rin ẹ̀dà tá a tẹ̀ jáde ní èdè méjìléláàádọ́fà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò tẹ̀ ẹ́ jáde mọ́ báyìí, o ṣì lè rí àwọn kókó pàtàkì inú rẹ̀ nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 wọ̀nyí: Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I? àti Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
O lè béèrè fún ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé pẹlẹbẹ yìí lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.