Àwọn ìdáhùn tó gbéṣẹ́ rèé sí àwọn ìbéèrè tó o ti ń béèrè!
• Eeṣe Ti Awọn Obi Mi Kò Fi Loye Mi?
• Eeṣe Tí Baba ati Mama Fi Pínyà?
• Bawo Ni Mo Ṣe Lè Ní Awọn Ọ̀rẹ́ Tootọ?
• Eeṣe Ti Mo Fi Maa Ń Sorikọ Tóbẹ́ẹ̀?
• Eeṣe Ti Awọn Ọ̀dọ́ Wọnyi Kò Jẹ́ Fi Mi Lọ́rùn Silẹ?
• Ki Ni Nipa Ti Ibalopọ Takọtabo Ṣaaju Igbeyawo?
Ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ kò láfiwé nínú gbogbo àwọn ìwé tó kù tí wọ́n ṣe fún àwọn ọ̀dọ́. A mú un jáde lẹ́yìn tá a ti ní ìjíròrò pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ jákèjádò ayé. Bẹ́ẹ̀ sì làwọn ìdáhùn rẹ̀, tá a gbé ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, gbéṣẹ́ gan-an ni! Àwọn ìbéèrè tó wà lókè yìí wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tí ìwé olójú ewé 320 yìí dáhùn.
Bó o bá fẹ́ ẹ̀dà kan ìwé yìí, kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.