ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g05 11/8 ojú ìwé 32
  • Ṣé Béèyàn Bá Ti Kú, Ó Kú Náà Nìyẹn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Béèyàn Bá Ti Kú, Ó Kú Náà Nìyẹn?
  • Jí!—2005
Jí!—2005
g05 11/8 ojú ìwé 32

Ṣé Béèyàn Bá Ti Kú, Ó Kú Náà Nìyẹn?

◼ Ọ̀pọ̀ èèyàn á fẹ́ láti rí ìdáhùn tó fini lọ́kàn balẹ̀ sáwọn ìbéèrè bíi: Ṣé béèyàn bá ti kú, ó kú náà nìyẹn? Ṣé ọkàn èèyàn lè kú? Kí ni Bíbélì tiẹ̀ sọ nípa àjíǹde sórí ilẹ̀ ayé?

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, obìnrin kan nílẹ̀ Faransé béèrè irú àwọn ìbéèrè yìí nínú lẹ́tà tó kọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé: “Ńṣe ni inú mi máa ń dùn láti ka àwọn ìwé yín, nítorí pé òótọ́ ni gbogbo àlàyé tó máa ń ṣe lórí onírúurú ọ̀ràn. Ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú téèyàn á rí bó bá ń ka Bíbélì máa ń mú káyé rọrùn fúnni.”

Obìnrin náà wá ṣàlàyé pé: “Lẹ́tà mi yìí dá lórí ìwé yín tó ní àkọlé náà, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú? Ìwé náà tù mí nínú lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó mú kí ohun gbogbo ṣe kedere kó sì rọrùn.” Ó wá fi kún un pé: “Màá fẹ́ kẹ́ ẹ fún mi ní mẹ́wàá tàbí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lára ìwé pẹlẹbẹ náà kí n lè pín in fáwọn èèyàn tí mo mọ̀, káwọn náà lè jàǹfààní látinú àwọn ohun tẹ́ ẹ kọ.”

A nírètí pé ìwọ náà á jàǹfààní látinú ìwé fífanimọ́ra, olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n náà, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?

Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́