“Ó Kàmàmà”
Ohun tí tọkọtaya kan tó ń gbé nílùú Georgia lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ nípa ìwé Kí ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? nìyẹn. Ọdún 2005 la tẹ ìwé olójú ewé igba o lé mẹ́rìnlélógún [224] tó ní àwòrán mèremère yìí jáde. Tọkọtaya náà tún sọ pé: “Níbi tí ìwé náà rọrùn dé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sì ẹni táwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ ò ní yé. Síbẹ̀, àkàgbádùn ló máa jẹ́ fáwọn ọ̀mọ̀wé torí pé fọ́fọ́ ni ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kún inú rẹ̀.”
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí tọkọtaya kan nílùú New Jersey lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tún jẹ́ ká rí bí orúkọ ìwé náà ṣe lè fa èèyàn lọ́kàn mọ́ra tó. Tọkọtaya náà gba ẹ̀dà kan ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ní àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wáyé nílùú Florida. Ìgbà tí àpéjọ yẹn sì parí, wọ́n wọkọ̀ òfuurufú lọ sí orílẹ̀-èdè Bahamas láti lọ lo àkókò ìsinmi wọn níbẹ̀. Aṣọ́bodè tó ń yẹ ẹrù wọn wò kófìrí ìwé náà, lẹ́yìn tó ka orúkọ rẹ̀, ó ní, “Ó pẹ́ tó ti ń wù mí láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí.” Inú aṣọ́bodè náà dùn gan-an nígbà tí tọkọtaya náà fún un ní ẹ̀dà kan tí wọ́n mú dání yàtọ̀ sí ẹ̀dà tiwọn fúnra wọn.
Lọ́jọ́ kejì, etíkun ni tọkọtaya tó lọ lo àkókò ìsinmi yìí wà tí wọ́n ń ka ìwé náà nígbà tí obìnrin kan tó ń tajà fáwọn tó wá ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ rí ìwé náà lọ́wọ́ wọn. Ó ní òun ti gbàdúrà lọ́jọ́ yẹn pé kí Ọlọ́run jẹ́ kóun lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà, ìyẹn, Kí ni Bíbélì fi kọ́ni gan-an? Ó béèrè bóun ṣe lè rí ẹ̀dà ìwé yẹn kan gbà, inú rẹ̀ sì dùn nígbà tí tọkọtaya náà fún un ní ẹ̀dà kan ṣoṣo tó kù yàtọ̀ sí tiwọn fúnra wọn.
Ní báyìí, a ti tẹ àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ogójì ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? jáde ní èdè márùnlélógóje [145]. Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.