ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/08 ojú ìwé 31
  • Ẹ̀rí Tó Ń Fi Hàn Lọ́jọ́ Gbogbo Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀rí Tó Ń Fi Hàn Lọ́jọ́ Gbogbo Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa
  • Jí!—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Ṣe Àṣàrò Lórí Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Tí Jèhófà Ní sí Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
    “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
  • Ǹjẹ́ O Gbà Pé Ọlọ́run Wà? Tó O Bá Gbà Àǹfààní Wo Ló Máa Ṣe Ẹ́?
    Jí!—2015
  • Bá A Ṣe Lè Dá Ìjọsìn Tòótọ́ Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 1/08 ojú ìwé 31

Ẹ̀rí Tó Ń Fi Hàn Lọ́jọ́ Gbogbo Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa

ÀWỌN ohun àràmàǹdà méje kan wà láyé ọjọ́un táwọn èèyàn kà sí àgbàyanu. Síbẹ̀, lára àwọn ohun àràmàǹdà méje wọ̀nyí, ilé aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tó wà ní Íjíbítì nìkan ló ṣẹ́ kù. Àmọ́ Bíbélì yàtọ̀ pátápátá sáwọn ohun àràmàǹdà wọ̀nyí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn bíi tiwa ni Ọlọ́run lò láti kọ ọ́, tó sì jẹ́ pé orí àwọn ohun èlò tó lè bà jẹ́ ni wọ́n kọ ọ́ sí, ó ṣì pé pérépéré títí dòní olónìí. Ọkàn wa balẹ̀ pátápátá pé ìwé tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí lè gbé ìgbàgbọ́ wa ró.—Aísáyà 40:8; 2 Tímótì 3:16, 17.

Bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe mú kí èrò rẹ̀ wà lákọọ́lẹ̀ mú kó dájú pé àṣìṣe kankan ò wọnú ọ̀rọ̀ rẹ̀ látàrí ìgbàgbé tó lè ṣe ẹ̀dá aláìpé. Yàtọ̀ síyẹn, bí àwọn tí Ọlọ́run lò láti kọ Bíbélì ṣe lo èdè tó rọrùn láti lóye mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé lè ka Bíbélì kó sì yé wọn. (Ìṣe 4:13) Kí lo ò bá tún retí pé kó wà nínú ìwé tí Ẹlẹ́dàá mí sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti kọ? Láfikún síyẹn, bó ṣe jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sẹ́ni tí kò ní Bíbélì jẹ́ ẹ̀rí pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí àwa ẹ̀dá èèyàn pọ̀ gan-an, láìka èdè wa tàbí ibi yòówù tá à ń gbé sí. (1 Jòhánù 4:19) Ó dájú pé bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ní Bíbélì lọ́wọ́ ò sọ ọ́ di ìwé yẹpẹrẹ, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló túbọ̀ buyì kún un!

Kódà àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì jẹ́ ká túbọ̀ mọ bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàlàyé bí ìgbésí ayé ẹ̀dá ṣe bẹ̀rẹ̀ láyé, ìdí tẹ́mìí àwa èèyàn ò fi gùn ju báyìí lọ, tó sì kún fún wàhálà, ó tún wá sọ bí Ọlọ́run yóò ṣe tipasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ yanjú àwọn ìṣòro wọ̀nyí. Àwọn ìmọ̀ràn rere tún wà nínú Bíbélì lórí báyé wa ṣe lè dùn bí oyin kódà nísinsìnyí. (Sáàmù 19:7-11; Aísáyà 48:17, 18) Paríparì rẹ̀ ni pé Bíbélì ṣàlàyé bí Ẹlẹ́dàá wa ṣe máa mú gbogbo ẹ̀gàn tí irọ́ Sátánì ti mú bá orúkọ rẹ̀ kúrò.—Mátíù 6:9.

Ìwé míì wo ló tún ṣàǹfààní, tó wúlò lóde òní, tó sì fi ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro ẹ̀dá hàn wá? Ṣó o wá rí i pé Bíbélì ò dà bí àwọn ohun àràmàǹdà méje ayé ọjọ́un tí wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ wọn nítorí àtimáa júbà àwọn ọlọ́run èké àtàwọn akọni ẹ̀dá. Ó jẹ́ ẹ̀rí tó ń fi hàn wá lọ́jọ́kọ́jọ́ pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwa èèyàn tó dá kò láàlà.

Tó ò bá tíì máa ka Ìwé Mímọ́, ṣe wàá kúkú bẹ̀rẹ̀ sí í kà á báyìí? Ní báyìí ná, kárí ayé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn tí iye wọn ju mílíọ̀nù mẹ́fà lọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Ó máa ń dùn mọ́ wọn nínú láti ran àwọn tó bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́wọ́, kí wọ́n lè fojú ara wọn rí i pé Bíbélì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé torí pé Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ló jẹ́.—1 Tẹsalóníkà 2:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́