Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
January-March 2008
Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Fífìyà Jẹ Àwọn Obìnrin?
Jákèjádò ayé làwọn èèyàn ń fìyà jẹ àwọn obìnrin tí wọ́n sì ń tẹ̀ wọ́n mẹ́rẹ̀. Àwọn ẹ̀sìn kan tiẹ̀ wà tí wọn ò róhun tó burú nínú kéèyàn máa rẹ́ àwọn obìnrin jẹ. Àmọ́, ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ọ̀rọ̀ náà?
3 Fífìyà Jẹ Àwọn Obìnrin Ti Di Ìṣòro Tó Kárí Ayé
4 Ojú Wo Ni Ọlọ́run Àti Kristi Fi Ń wo Àwọn Obìnrin?
28 Ọjọ́ Ti Pẹ́ Táwọn Èèyàn Ti Mọ Orúkọ Ọlọ́run
30 Ẹ̀kọ́ Èké àbí Òótọ́ Pọ́ńbélé?
31 Ẹ̀rí Tó Ń Fi Hàn Lọ́jọ́ Gbogbo Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa
32 Ó Fẹ́ràn Rẹ̀ Ju Ohun Ìṣeré Èyíkéyìí Lọ
Ṣó Yẹ Kí N Máa Ṣeré Orí Kọ̀ǹpútà? 24
Ìwà ipá àti ìbálòpọ̀ ni ọ̀pọ̀ eré orí kọ̀ǹpútà ń gbé lárugẹ báyìí. Báwo ni ẹni tó gba ẹ̀kọ́ Kristi gbọ́ ṣe lè máa mọ èyí tó bọ́gbọ́n mu pé kóhun ṣe nínú àwọn eré náà? Báwo ló sì ṣe yẹ kó máa pẹ́ nídìí ẹ̀ tó? Ṣé ohun kan tiẹ̀ wà téèyàn lè máa ṣe dípò eré orí kọ̀ǹpútà?