ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/10 ojú ìwé 3
  • “Ó Ti Sú Mi!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ó Ti Sú Mi!”
  • Jí!—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ìjì Tó Ń Jà Yìí Ò Ní Í Gbé Ìgbéyàwó Lọ?
    Jí!—2006
  • Híhá Sínú Ìgbéyàwó Aláìnífẹ̀ẹ́
    Jí!—2001
  • Ṣé Ìkọ̀sílẹ̀ Ló Máa Yanjú Ìṣòro Yín?
    Jí!—2004
  • Ipa Tí Ìkọ̀sílẹ̀ Máa Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọ
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
Àwọn Míì
Jí!—2010
g 4/10 ojú ìwé 3

“Ó Ti Sú Mi!”

Bá a bá pa ilé kan tì, tá ò bójú tó o, bó pẹ́ bó yá ilé ọ̀hún á di ahẹrẹpẹ. Òjò àti oòrùn lè ti pa ilé náà fún ọ̀pọ̀ ọdún, síbẹ̀ kò wó. Àmọ́ ó ti di ahẹrẹpẹ, ó sì jọ pé kò ní pẹ́ dà wó.

ÀPÈJÚWE yìí bá ọ̀pọ̀ ìdílé mu lóde òní. Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹ́ rí bíi pé ìgbéyàwó rẹ ti di ahẹrẹpẹ tí kò sì ní pẹ́ dà wó? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, mọ̀ dájú pé kò sí tọkọtaya tí kì í ní ìṣòro. Kódà, Bíbélì sọ ní kedere pé àwọn tó bá gbéyàwó á ní “ìpọ́njú.”—1 Kọ́ríńtì 7:28.

Ohun tí ẹgbẹ́ olùwádìí kan sọ fi hàn pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ yìí, wọ́n ní: “Ìgbéyàwó ni ohun tó léwu jù lọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé sábà máa ń tọrùn bọ̀.” Wọ́n tún fi kún un pé: “Àjọṣe téèyàn fi ayọ̀ bẹ̀rẹ̀, tí ọkàn èèyàn sì balẹ̀ pé nǹkan á yọrí sí dáadáa, á wá di èyí tó ń fayé súni tó sì ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni gidigidi.”

Báwo ni ìgbéyàwó tìẹ ṣe rí? Ǹjẹ́ o máa ń kojú irú àwọn ìṣòro tá a tò sí ìsàlẹ̀ yìí nínú ìgbéyàwó rẹ?

● Àríyànjiyàn nígbà gbogbo

● Ọ̀rọ̀ tó ń dunni wọra

● Àìṣòótọ́

● Ìbínú

Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ìgbéyàwó rẹ ti di ahẹrẹpẹ, tó sì dà bíi pé kò ní pẹ́ dà wó, kí ló yẹ kó o ṣe? Ṣé ìkọ̀sílẹ̀ ló wá kàn?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

“ÌKỌ̀SÍLẸ̀ TI DI OHUN TÓ Ń ṢẸLẸ̀ LÓJOOJÚMỌ́”

Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ìkọ̀sílẹ̀ ti wá di mẹ́ta kọ́bọ̀. Àpẹẹrẹ kan ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, níbi tí ìkọ̀sílẹ̀ kò ti wọ́pọ̀ nígbà kan. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Barbara Dafoe Whitehead sọ nínú ìwé rẹ̀, The Divorce Culture pé: “Lẹ́yìn ọdún 1960, ńṣe ni iye àwọn tó ń kọra wọn sílẹ̀ ṣàdédé ga sókè. Láàárín nǹkan bí ọdún mẹ́wàá, iye àwọn tó ń kọra wọn sílẹ̀ di ìlọ́po méjì, ó sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i títí di ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980, tí ìkọ̀sílẹ̀ pọ̀ jù lọ láàárín àwọn ará Yúróòpù àti Amẹ́ríkà. Látàrí bí iye àwọn tọkọtaya tó ń kọra wọn sílẹ̀ ṣe ṣàdédé lọ sókè tí kò sì wálẹ̀ mọ́ yìí, láàárín ọgbọ̀n ọdún ìkọ̀sílẹ̀ ti di ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ láàárín àwọn ará Amẹ́ríkà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́