“Ẹ Ṣeun Tẹ́ Ẹ Fi Bàbá Tó Nífẹ̀ẹ́ Wa Hàn Mí”
● Ọmọbìnrin ọdún mọ́kàndínlógún kan tó ń gbé ní gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ọ̀dọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ni mo gbé dàgbà, mo sì gba Kristi ní Olùgbàlà mi. Àmọ́, fún ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ń bẹ̀rù ọjọ́ tí Ọlọ́run máa ṣèdájọ́ ayé tó sì máa sun àwọn èèyàn nínú iná ọ̀run àpáàdì. Nígbà tó yá mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé yín, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
“Lẹ́yìn tí mo ka orí mélòó kan, ńṣe lara tù mí pẹ̀sẹ̀. À fi bíi pé wọ́n gbé ẹrù tó wúwo gan-an kúrò ní àyà mi. Mo wá rí i pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, onínúure àti aláàánú. Ó fẹ́ kí n jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun, àmọ́ kì í ṣe èyí táá mú kí ẹ̀rù máa bà mí. Mò ń gbèrò láti lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́jọ́ Sunday tó ń bọ̀ yìí! Inú mi ń dùn gan-an. Ẹ ṣeun tẹ́ ẹ fi Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ wa hàn mí, kì í ṣe ẹni tó dá iná ọ̀run àpáàdì.
Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tún jíròrò àwọn kókó pàtàkì míì. Lára wọn ni ipò tí àwọn òkú wà, ìrètí àjíǹde, béèyàn ṣe lè mú kí ìgbé ayé ìdílé rẹ̀ sunwọ̀n sí i, ẹni tí Ọlọ́run àti Jésù Kristi jẹ́ àti ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà. Tó o bá fẹ́ ìwé yìí, kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sí ojú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Mo fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé yìí.
Kọ èdè tó o fẹ́.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.