ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g16 No. 5 ojú ìwé 10-11
  • Kẹ́míkà Àgbàyanu Tó Ń Jẹ́ Carbon

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kẹ́míkà Àgbàyanu Tó Ń Jẹ́ Carbon
  • Jí!—2016
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Àǹfààní Tí À Ń Rí Nínú Igbó Ṣe Pọ̀ Tó?
    Jí!—2004
  • Èé Ṣe Tí Dáyámọ́ńdì Fi Gbówó Lórí Tó Bẹ́ẹ̀?
    Jí!—1997
Jí!—2016
g16 No. 5 ojú ìwé 10-11

Kẹ́míkà Àgbàyanu Tó Ń Jẹ́ Carbon

Carbon atoms

Ìwé kan tí wọ́n ń pè ní Nature’s Building Blocks sọ pé: “Kò sí nǹkan míì tó ṣàǹfààní fún ìwàláàyè àwọn nǹkan ẹlẹ́mìí tó carbon.” Ìdí sì ni pé carbon ní àwọn èròjà tó lè mú kó lẹ̀ mọ́ra, ó sì tún lè lẹ̀ mọ́ àwọn èròjà míì láti mú ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù kẹ́míkà jáde. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ṣàwárí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ báyìí àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n tún lè fi ṣe.

Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn èròjà inú carbon lè lẹ̀ mọ́ra kí wọ́n sì jáde ní oríṣiríṣi ọ̀nà. Wọ́n lè so kọ́ra bí ṣéènì tàbí kí wọ́n rí roboto tàbí pẹrẹsẹ tàbí gbọọrọ. Tẹ̀gàn ni hẹ̀, kẹ́míkà àgbàyanu ni carbon!

DÁYÁMỌ́ǸDÌ

Dáyámọ́ǹdì

Àwọn èròjà inú carbon tún máa ń lẹ̀ mọ́ra tí wọ́n á sì gbé igun mẹ́rin jáde èyí tí wọ́n ń pè ní tetrahedrons, èyí máa ń rí ṣóńṣó lókè, á sì ṣe fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ nísàlẹ̀, á tún wá le gbagidi. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé dáyámọ́ǹdì ló le jù láyé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, èròjà kan ṣoṣo lára carbon ni dáyámọ́ǹdì jẹ́.

GRAPHITE

Pẹ́ńsù

Graphite ni wọ́n ń pe kẹ́míkà tó máa jáde tí àwọn èròjà inú carbon kò bá lẹ̀ mọ́ra dáadáa tó. Èyí lè mú kí wọ́n ní àyè débi pé wọ́n á lè yọ̀ kúrò lórí ara wọn bí ìgbà tí bébà bá ń yọ̀ lórí ara wọn. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń lo graphite láti ṣe gírísì tàbí lẹ́ẹ̀dì inú pẹ́ńsù.a

GRAPHENE

Ilà tí wọ́n fi pẹ́ńsù fà

Nígbà míì, àwọn èròjà carbon lè lẹ̀ mọ́ra láti mú abala kan tó dà bíi nẹ́ẹ̀tì pẹrẹsẹ jáde táá sì ní igun mẹ́fà, èyí ni wọ́n ń pè ní Graphene. Kẹ́míkà graphene yìí máa ń lágbára fíìfíì ju irin lọ. Ìwádìí fi hàn pé tí wọ́n bá fi pẹ́ńsù fàlà, graphene díẹ̀ máa wà nínú ilà náà.

FULLERENES

Fullerenes

Èròjà carbon tó máa ń ní ihò láàárín ni wọ́n ń pè ní fullerenes. Ó máa ń rí roboto bíi bọ́ọ̀lù tàbí kó rí gbọọrọ bíi páìpù, ó sì máa ń kéré gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ìwọ̀n mítà tí wọ́n ń pè ní nanometer ni wọ́n máa ń fi wọn fullerenes torí bó ṣe kéré tó.

NǸKAN ẸLẸ́MÌÍ

Nǹkan ẹlẹ́mìí tó ní carbon

Ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ sẹ́ẹ̀lì tó wà nínú àwọn ewéko, ẹranko àti èèyàn ló ní carbon nínú. Ó sì tún wà nínú èròjà carbohydrates, amino acid àti ọ̀rá.

“Àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere . . . nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá.” ​—Róòmù 1:20.

a Wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Does Anyone Have a Pencil?” nínú Jí! July 2007, lédè Gẹ̀ẹ́sì.

Ìràwọ̀

Ibo Ni Carbon Ti Wá?

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé èròjà tó wà nínú ohun kan tí wọ́n ń pè ní helium ló máa ń para pọ̀ di carbon. Bẹ́ẹ̀, wọ́n gbà pé àtinú ìràwọ̀ kan tó ń jẹ́ red giants ni helium yìí ti wá. Àmọ́ kí àwọn èròjà yẹn tó lè lẹ̀ pọ̀ di carbon, àwọn nǹkan kan wà tí kò gbọ́dọ̀ yí pa dà. Nígbà tí onímọ̀ físíìsì kan tó ń jẹ́ Paul Davies ń sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí, ó ní: “Bí àyípadà bá ṣẹlẹ̀ sí ìlànà tó ń darí àgbáyé wa, kódà kó jẹ́ bíńtín bí orí abẹ́rẹ́, ṣe ni gbogbo nǹkan máa pa rẹ́ ráúráú. Kò ní sí nǹkan ẹlẹ́mìí kankan mọ́.” Báwo wá ni gbogbo èyí ṣe lè ṣeé ṣe? Àwọn kan sọ pé ó kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn míì sì gbà pé Ẹlẹ́dàá kan tó gbọ́n ló ṣe é. Èrò ta ni ìwọ gbà pé ó tọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́