Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀
Ohun Méjìlá Tó Ń Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
A máa ń gbọ́ nípa ohun tó fà á táwọn ìdílé kan fi tú ká. Àmọ́ àwọn ìdílé tó ń láyọ̀ ńkọ́, kí ló ń ràn wọ́n lọ́wọ́?
- Láàárín ọdún 1990 sí 2015, iye àwọn tó jẹ́ ẹni àádọ́ta ọdún [50] tó kọ ara wọn sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti fi ìlọ́po méjì ju ti tẹ́lẹ̀, nígbà tí àwọn tó jẹ́ ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́ta [65] tó kọ ara wọn sílẹ̀ lọ sókè ní ìlọ́po mẹ́ta. 
- Àwọn òbí ò mọ ohun tí wọ́n máa ṣe mọ́: Àwọn kan sọ pé kí wọ́n máa gbóríyìn fáwọn ọmọ wọn ní gbogbo ìgbà, àwọn míì sọ pé kí wọ́n má ṣe gba gbẹ̀rẹ́ fún wọn rárá. 
- Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò mọ àwọn nǹkan tó lè mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí bí wọ́n ṣe ń dàgbà. 
Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé . . .
- Ìdílé lè láyọ̀, kó sì wà pẹ́ títí. 
- Àwọn òbí lè kọ́ bí wọ́n ṣe lè fi ìfẹ́ bá àwọn ọmọ wọn wí. 
- Àwọn ọ̀dọ́ sì lè kọ́ àwọn nǹkan tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń dàgbà. 
Àmọ́ báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Ẹ̀dà Jí! yìí máa sọ̀rọ̀ nípa ohun méjìlá tó máa jẹ́ kí ìdílé rẹ láyọ̀.