Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀
Ohun Mẹ́fà Tó Yẹ Ká Kọ́ Àwọn Ọmọ
Irú èèyàn wo lo fẹ́ káwọn ọmọ rẹ jẹ́ tí wọ́n bá dàgbà?
- Ẹni Tó Máa Ń Kó Ara Rẹ̀ Níjàánu 
- Onírẹ̀lẹ̀ 
- Ẹni Tó Ní Ìforítì 
- Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé 
- Ọlọ́gbọ́n 
- Olóòótọ́ 
Àwọn ọmọ ò lè ṣàdédé ní àwọn ìwà ọmọlúwàbí yìí. Àfi kó o kọ́ wọn.
Ìwé yìí sọ̀rọ̀ nípa ohun pàtàkì mẹ́fà tó yẹ kó o kọ́ àwọn ọmọ rẹ. Àwọn nǹkan náà sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an nígbà tí wọ́n bá dàgbà.