BÓ O ṢE LÈ NÍ ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN
Kí Ló Ń Fa Àìbalẹ̀ Ọkàn?
Ilé ìwòsàn tó ń jẹ́ Mayo Clinic sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn àgbàlagbà ni ọkàn wọn kì í balẹ̀. Láyé tá a wà yìí, oríṣiríṣi àyípadà ló lè dé bá ẹnikẹ́ni.” Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn àyípadà tó ń fa àìbalẹ̀ ọkàn:
- ìkọ̀sílẹ̀ 
- ikú èèyàn ẹni 
- àìsàn tó le 
- jàǹbá burúkú 
- ìwà ọ̀daràn 
- wàhálà ìgbésí ayé 
- àwọn àjálù tó dédé wáyé àti èyí táwọn èèyàn ń fà 
- ìdààmú nílé ẹ̀kọ́ àti níbi iṣẹ́ 
- àníyàn nípa iṣẹ́ àti owó