APÁ 4
Láti Ìgbà Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì sí Ìgbà Ìgbèkùn ní Bábílónì
Sọ́ọ̀lù di ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n Jèhófà kọ̀ ọ́, ó sì yan Dáfídì ní ọba dípò rẹ̀. A ó mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Dáfídì. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó bá Gòláyátì òmìrán jà. Nígbà tó yá, ó sá lọ fún Sọ́ọ̀lù Ọba òjòwú. Lẹ́yìn náà, Ábígẹ́lì arẹwà kò jẹ́ kó hùwà búburú kan.
Lẹ́yìn èyí, a ó mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan nípa Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì, ẹni tó gba ipò Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì. Ogójì ọdún ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọba mẹ́ta àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì fi jọba. Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì kú, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pín sí ìjọba méjì, ìjọba àríwá àti ìjọba gúúsù.
Igba ọdún ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [257] ni Ìjọba àríwá, tó ní ẹ̀yà mẹ́wàá, fi wà kí àwọn ará Ásíríà tó pa á run. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún ó lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [133] lẹ́yìn náà ni Ìjọba ìhà gúúsù tó ní ẹ̀yà méjì pẹ̀lú pa run. Àkókò yìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì. Nítorí náà, ìtàn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ó lé mẹ́wàá [510] ló wà ní Apá KẸRIN. Lákòókò yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣẹlẹ̀.