Èèpo Ẹ̀yìn Ìwé
ÌDÍLÉ ni ìgbékalẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ tí a mọ̀, ṣùgbọ́n lónìí, ó ti ko ìṣòro. Ìjoògùnyó àti ìwà pálapàla àwọn ọ̀dọ́langba tí ń tàn kálẹ̀ lọ́nà bíbanilẹ́rù, ìyọnu òde òní ti ìkọ̀sílẹ̀ àti ìwà ipá nínú ìdílé, àwọn ìdílé olóbìí kan tí ń gbèèràn bí iná ọyẹ́, àti àwọn ìṣòro kàǹkà-kàǹkà mìíràn, ń mú kí àwọn kan ṣe kàyéfì bí ìdílé bá lè rù ú là.
Ó ha ṣì ṣeé ṣe kí ìdílé jẹ́ ibì kan tí ó fìdí múlẹ̀, tí ó sì fi àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ ni, bí àwọn mẹ́ńbà ìdílé bá mọ àṣírí ayọ̀ ìdílé ní tòótọ́. Àṣírí yìí kì í ṣe èyí tí ó pa mọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rúndún ni a ti fi dán an wò tí ó sì gbéṣẹ́. Kí ni àṣírí náà? Ìwé yìí, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, pèsè ìdáhùn rẹ̀. Ó tún pèsè àwọn àpẹẹrẹ tí ó ṣeé mú lò nípa bí “àṣírí” yìí ṣe lè ṣèrànwọ́ láti yanjú ọ̀pọ̀ àwọn ipò akaniláyà nínú ìdílé. Ta wá ni kò nílò irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ lónìí?