Bí A Óò Ṣe Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Yìí
A pète ìwé yìí fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Báwo ni a óò ṣe lò ó? A dámọ̀ràn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó tẹ̀ lé e yìí: Àwọn ìbéèrè wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan. Ìwọ yóò rí nọ́ḿbà àwọn ìpínrọ̀ tí àwọn ìdáhùn wà, nínú àkámọ́ lẹ́yìn ìbéèrè kọ̀ọ̀kan. Kọ́kọ́ ka àwọn ìbéèrè náà. Ronú nípa wọn. Lẹ́yìn náà, ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, kí o sì wo àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ náà nínú Bibeli rẹ. Lẹ́yìn tí o bá ti parí ẹ̀kọ́ kan, padà sí àwọn ìbéèrè náà, kí o sì gbìyànjú láti rántí ìdáhùn Bibeli sí ìbéèrè kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí o bá ti parí ìwé pẹlẹbẹ náà látòkèdélẹ̀, padà sẹ́yìn, kí o sì ṣàtúnyẹ̀wò gbogbo ìbéèrè náà.