Ìwé Kan Tí Ó Yẹ Ní Kíkà
Ọ̀jọ̀gbọ́n yunifásítì kan sọ fún ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tí kò fọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ pé: “Kò yẹ kí a fọwọ́ dan-indan-in mú Bíbélì.”
Obìnrin náà béèrè pé: “Ǹjẹ́ o ti ka Bíbélì rí?”
Bí ó ti bá ọ̀jọ̀gbọ́n náà lójijì, ó jẹ́wọ́ pé òun kò kà á rí.
“Báwo ni o ṣe lè fi ìdánilójú hán-únhán-ún sọ nǹkan kan nípa ìwé tí o kò kà rí?”
Òdodo ọ̀rọ̀ ni obìnrin yìí sọ. Ọkùnrin náà pinnu láti ka Bíbélì kí ó tó wá ní èrò kan lọ́kàn nípa rẹ̀.
BÍBÉLÌ, tí ó ní ìwé 66 nínú, ni a ṣàpèjúwe pé “ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àkójọ ìwé tí ó tí ì ní agbára ìdarí tí ó ga jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn.”1 Ní ti gidi, ó ti nípa lórí àwọn kan nínú iṣẹ́ ọ̀nà, ìwé kíkọ, àti orin ayé tí ó ga lọ́lá jù lọ. Ó ti nípa tí ó jọjú lórí òfin. A ti kan sáárá sí i nítorí ìgbékalẹ̀ ọ̀nà ìgbàkọ̀wé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àgbà ọ̀mọ̀wé sì ti gbé e gẹ̀gẹ̀. Ipa tí ó ti ní lórí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn ní gbogbo ẹ̀ka láwùjọ jẹ́ èyí tí ó jinlẹ̀ gidigidi. Ó ti gbin ẹ̀mí ìdúróṣinṣin tí ó ga dé ìwọ̀n kan sínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ń kà á. Àwọn kan tilẹ̀ ti fẹ̀mí wewu ikú kí wọn ṣáà lè kà á.
Lẹ́sẹ̀ kan náà, àìní ìdánilójú wà nípa Bíbélì. Àwọn ènìyàn wà tí wọ́n ní èrò pàtó kan nípa rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn fúnra wọn kò tí ì kà á rí. Wọ́n lè jẹ́wọ́ jíjẹ́ òtítọ́ ìwúlò rẹ̀ ní ti ìgbékalẹ̀ ọ̀nà ìgbàkọ̀wé tàbí ti ìtàn, ṣùgbọ́n wọn ń ṣe kàyéf ì nípa: Báwo ni ìwé kan tí a kọ ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ṣe lè já mọ́ nǹkan kan ní ayé òde òní? A ń gbé ní “ayé tí ìsọfúnni gbilẹ̀.” A ń rí ìsọfúnni ní gbígbóná fẹlifẹli lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ àti ti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ gbà lárọ̀ọ́wọ́tó. Ìmọ̀ràn àwọn “ògbógi” lórí ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìṣòro ìgbésí ayé òde òní wà lárọ̀ọ́wọ́tó fàlàlà. Ní tòótọ́, Bíbélì ha lè ní ìsọfúnni tí ó gbéṣẹ́ lóde òní nínú bí?
Ìwé pẹlẹbẹ yìí gbìyànjú láti dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀. A kò wéwèé rẹ̀ pé kí ó gbé ojú ìwòye tàbí ìgbàgbọ́ ìsìn kà ọ́ lórí, ṣùgbọ́n a pète rẹ̀ pé kí ó fi hàn pé, Bíbélì, ìwé tí ó nípa lórí ẹni ní ti ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ yí yẹ fún àgbéyẹ̀wò rẹ. Àtẹ̀jáde kan tí a tẹ̀ ní 1994 sọ̀rọ̀ àkíyèsí pé àwọn olùkọ́ni kan fi taratara ní èròǹgbà náà pé Bíbélì rinlẹ̀ nínú àṣà ìbílẹ̀ àwọn ará Ìlà Oòrùn tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí “ẹnikẹ́ni, yálà onígbàgbọ́ tàbí aláìgbàgbọ́, kò bá mọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ àti ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì, yóò jẹ́ òpè nínú ọ̀ràn ti àṣà ìbílẹ̀.”2
Bóyá, lẹ́yìn kíka ohun tí a tẹ̀ síhìn-ín, ìwọ yóò gbà pé—bóyá ẹnì kan jẹ́ onísìn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́—Bíbélì jẹ́, ó kéré pin, ìwé kan tí ó yẹ ní kíkà.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
“Mo rí ìlàlóye mi gbà ní ti gidi nípa kíka ìwé kan.—Ìwé kan kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ìwé ògbólógbòó kan tí ó rọrùn sì ni, tí kò lọ́jú pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ kò ti lọ́jú pọ̀, ó sì tuni lára . . . Orúkọ ìwé yìí ní wẹ́rẹ́ sì ni Bíbélì.”—Heinrich Heine, òǹkọ̀wé ti ọ̀rúndún kọkàndínlógún, tí ó jẹ́ ará Germany.3