ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ol ojú ìwé 2
  • Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú
  • Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
ol ojú ìwé 2

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ ni Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Ọwọ́ rẹ̀ ni ìwàláàyè wa ìsinsìnyí àti ti ọjọ́ iwájú wà. Ó lágbára láti sanni lẹ́san rere, ó sì lágbára láti fìyà jẹni. Ó lágbára láti fúnni ní ìyè, ó sì lágbára láti gbà á. Bí a bá rí ojú rere rẹ̀, a ó ṣe àṣeyọrí sí rere; bí èèyàn ò bá rí ojú rere rẹ̀, a jẹ́ pé ó parí fónítọ̀hún nìyẹn. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí ìjọsìn wa ní ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀!

Ìdílé kan dúró sí ibi tí ọ̀nà ti pín sí méjì

Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn èèyàn ń gbà jọ́sìn. Bí ìsìn bá dà bí ọ̀nà, ǹjẹ́ gbogbo ọ̀nà ìjọsìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà? Rárá o, kì í ṣe gbogbo wọn. Jésù, tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run fi hàn pé ọ̀nà méjì péré ní gbogbo wọ́n pín sí. Ó sọ pé: “Aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.”​—Mátíù 7:13, 14.

Oríṣi ìsìn méjì péré ló wà: ọ̀kan ń sinni lọ sí ìyè, èkejì sì ń sinni lọ sí ìparun. Ohun tí ìwé pẹlẹbẹ yìí wà fún ni pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́