Ara Èèpo Ẹ̀yìn Ìwé
ỌJỌ́ JÈHÓFÀ . . . ni ẹṣin ọ̀rọ̀ táwọn ìwé méjìlá tó kẹ́yìn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ lásọtúnsọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ ohun tó wà nínú àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn, àmọ́ o lè rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́ nínú wọn, èyí tó o lè máa fi sílò lójoojúmọ́. Ǹjẹ́ o mọ bó o ṣe lè rí i? Báwo sì ni àwọn ìwé méjìlá náà ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè múra sílẹ̀ fún ọjọ́ ńlá Jèhófà?