Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ̀ Sí I?
Ìwé pẹlẹbẹ yìí ṣe àkópọ̀ àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì fún wa lọ́nà tó ṣe ṣókí, tó sì tẹ̀ léra ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Àmọ́ ṣá o, ìwé yìí ò ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lórí kókó ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan o.
Bí àpẹẹrẹ, o lè fẹ́ mọ ìdáhùn Bíbélì sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí: Ṣóòótọ́ ni Ọlọ́run bìkítà nípa mi? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a bá kú? Báwo ni mo ṣe lè láyọ̀ nígbèésí ayé mi?
Ìdáhùn sí èyí àtàwọn ìbéèrè fífani lọ́kàn mọ́ra míì wà nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. A ṣe é láti mú kó o máa fi Bíbélì jíròrò kókó ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Bó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yìí wàá lè rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan. O lè béèrè fún ẹ̀dà kan ìwé yìí lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ẹ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ìwé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sísàlẹ̀ yìí.
Mo fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? pẹ̀lú/tàbí ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ www.jw.org/yo.