Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú
Ǹjẹ́ O Ti Ronú Nípa Ìbéèrè Yìí Rí?
Ẹ̀kọ́ wo gan-an ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run?
Kí lo lè ṣe láti mú kí ìdílé rẹ jẹ́ aláyọ̀?
Kí nìdí tí ìṣòro fi pọ̀ nínú ayé?
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé?
Torí kí ni Ọlọ́run ṣe dá ilẹ̀ ayé?
Ibo ni àwọn tó ti kú wà?
Kí ni àwọn áńgẹ́lì máa ń ṣe fún wa?
Báwo ni o ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run?
Àwọn èèyàn tó pọ̀ rẹpẹtẹ ló rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn sí ìbéèrè wọ̀nyí nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwé Mímọ́. Ìwọ náà lè rí ìdáhùn tí yóò tẹ́ ọ lọ́rùn.
Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, lo sí ìkànnì www.jw.org/yo, tàbí kó o kàn sí ẹni tó fún ọ ní ìwé yìí.