Orin 143
Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ayé Tó Ṣókùnkùn
Bíi Ti Orí Ìwé
	- Láyé burúkú tá a wà yìí, - Ìmọ́lẹ̀ wà tá à ń rí. - Bíi pé ojúmọ́ ń mọ́ bọ̀ - Tó máa mọ́ kedere. - (ÈGBÈ) - Iṣẹ́ ìwàásù wa, - Mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn. - Ó ń mú ìrètí wá— - Ó ń mọ́lẹ̀, ó ń tàn yòò, - Ó ń mú ká lè rí ọ̀la— - Òkùnkùn lọ. 
- Ó yẹ ká jí àwọn tó ń sùn - Torí àkókò ń lọ. - À ń gbé wọn ró, wọ́n ń nírètí. - À ń fi wọ́n sádùúrà. - (ÈGBÈ) - Iṣẹ́ ìwàásù wa, - Mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn. - Ó ń mú ìrètí wá— - Ó ń mọ́lẹ̀, ó ń tàn yòò, - Ó ń mú ká lè rí ọ̀la— - Òkùnkùn lọ. 
(Tún wo Jòh. 3:19; 8:12; Róòmù 13:11, 12; 1 Pét. 2:9.)