Orin 145
À Ń Múra Láti Lọ Wàásù
Bíi Ti Orí Ìwé
	- Ilẹ̀ mọ́. - Láìpẹ́, a máa - Jáde lọ sóde ẹ̀rí. - Àmọ́ òjò ṣú, - Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. - Ó lè wù wá ká dúró sílé, - ká sì sùn. - (ÈGBÈ) - Èrò tó tọ́, ìmúrasílẹ̀, - Àtàdúrà gbígbà; - Ìwọ̀nyí lè fún wa ní okun, - Tí a nílò. - Àwọn áńgẹ́lì wà lẹ́yìn wa. - Jésù ló ń darí wọn. - Pẹ̀lú ẹni tá a jọ máa ṣiṣẹ́, - A ó ṣe é yọrí. 
- A ó rí i pé - A máa láyọ̀ - Tá a bá fi nǹkan yìí sọ́kàn. - Jèhófà sì ń rí - Gbogbo ipá tá à ń sà, - A mọ̀ pé kò ní gbàgbé ìfẹ́; - tá a fi hàn. - (ÈGBÈ) - Èrò tó tọ́, ìmúrasílẹ̀, - Àtàdúrà gbígbà; - Ìwọ̀nyí lè fún wa ní okun, - Tí a nílò. - Àwọn áńgẹ́lì wà lẹ́yìn wa. - Jésù ló ń darí wọn. - Pẹ̀lú ẹni tá a jọ máa ṣiṣẹ́, - A ó ṣe é yọrí. 
(Tún wo Oníw. 11:4; Mát. 10:5, 7; Lúùkù 10:1; Títù 2:14.)