Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé?
Ṣé o rò pé . . .
- inú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ni? 
- àbí inú ìmọ̀ ọgbọ́n orí? 
- àbí inú Bíbélì? 
Ọ̀KAN LÁRA ÀWỌN TÓ KỌ BÍBÉLÌ SỌ FÚN ỌLỌ́RUN PÉ
“Fún mi ní òye . . . Òtítọ́ ni . . . ọ̀rọ̀ rẹ.”—Sáàmù 119:144, 160, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
Bíbélì ń dáhùn ìbéèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.
Ṣé wàá fẹ́ kó dáhùn tìẹ náà?
Ìkànnì jw.org/yo máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.
KA àwọn ohun tó wà lórí ìkànnì náà
- Bíbélì wà níbẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè 
- Ìdáhùn àwọn ìbéèrè látinú Bíbélì 
- Ìrànlọ́wọ́ tó wà fún àwọn ìdílé 
WO àwọn fídíò tó dá lórí Bíbélì
- Ẹ̀kọ́ àti àwọn orin tó wà fún àwọn ọmọdé 
- Ìmọ̀ràn tó wà fún àwọn ọ̀dọ́ 
- Ìgbàgbọ́ tó lágbára 
WA àwọn ìwé jáde
- Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! 
ÈWO LÁRA ÀWỌN ÌBÉÈRÈ PÀTÀKÌ YÌÍ LÓ Ń JẸ Ọ́ LỌ́KÀN JÙ LỌ?
- Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa? 
- Ṣé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé? 
- Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá kú? 
Wàá rí ìdáhùn látinú Bíbélì sí àwọn ìbéèrè yìí lórí ìkànnì jw.org/yo.
(Lọ sí Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ › OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ)