ORIN 85
Ẹ Fayọ̀ Tẹ́wọ́ Gba Ara Yín
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. A kí yín káàbọ̀ sí Gbọ̀ngàn ‘jọba, - Gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ wá jọ́sìn Jáà. - Ìpèsè oúnjẹ tẹ̀mí wà fún wa; - Ìpéjọ wa ládùn, ó lóyin, à ń kẹ́kọ̀ọ́. 
- 2. A mọrírì àwọn arákùnrin - Tó ń múpò ‘wájú nínú ìjọ. - Ẹni ọ̀wọ́n tí Jáà fún wa ni wọ́n, - Bí wọ́n ṣe ń bójú tó iṣẹ́ táa yàn fún wọn. 
- 3. À ń ké sí gbogbo orílẹ̀-èdè - Kí wọ́n lè wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. - Jèhófà àti Jésù ló ń fà wá; - Ká fi tọkàntọkàn tẹ́wọ́ gba ara wa. 
(Tún wo Jòh. 6:44; Fílí. 2:29; Ìfi. 22:17.)