ORIN 117
Ìwà Rere
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà, Ẹniire ni ọ́; - Adúróṣinṣin ni ọ́. - Ìgbà gbogbo lò ń bù kún wa; - Gbogbo ọ̀nà rẹ ló dáa. - O máa ń fojúure hàn sí wa - Bí a tiẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. - Ìwọ nìkan lògo tọ́ sí; - Aó máa fayọ̀ jọ́sìn rẹ. 
- 2. Àwa tá a jẹ́ ènìyàn rẹ - Ńfara wé inúure rẹ. - Ó máa ń hàn nínú ìwà wa - Àtiṣẹ́ ‘wàásù tá à ńṣe. - Ẹ̀kọ́ rẹ ń ṣe wá láǹfààní, - Ó ń sèso kárí ayé. - Jọ̀ọ́, fún wa lẹ́mìí mímọ́ rẹ - Ká lè máa hùwà rere. 
- 3. Jọ̀wọ́, bù kún wa Jèhófà - Bí a ṣe ń hùwà rere - Sáwọn ará níbi gbogbo, - Lọ́kùnrin àtobìnrin. - Fi ẹ̀mí rẹ ràn wá lọ́wọ́ - Ká lè máa hùwà rere - Nínú ilé, nínú ìjọ, - Ládùúgbò, níbi gbogbo. 
(Tún wo Sm. 103:10; Máàkù 10:18; Gál. 5:22; Éfé. 5:9.)