ORIN 145
Ọlọ́run Ṣèlérí Párádísè
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà ṣe ìlérí fún wa - Páyé máa di Párádísè. - Kristi ló máa jẹ́ alákòóso, - Kò ní síkú àtẹ̀ṣẹ̀ mọ́. - (ÈGBÈ) - Ayé yóò di Párádísè. - Pẹ̀lú ‘gbàgbọ́, ó dájú pé - Ó máa rí bẹ́ẹ̀. Jésù yóò ṣeé, - Torí pó máa ńṣe ìfẹ́ Jáà. 
- 2. Kò ní pẹ́ mọ́ nínú ayé yìí, - Jésù yóò jí òkú dìde. - Jésù ti sọ pé: ‘Ìwọ yóò wà - Pẹ̀lú mi ní Párádísè.’ - (ÈGBÈ) - Ayé yóò di Párádísè. - Pẹ̀lú ‘gbàgbọ́, ó dájú pé - Ó máa rí bẹ́ẹ̀. Jésù yóò ṣeé, - Torí pó máa ńṣe ìfẹ́ Jáà. 
- 3. Jésù ṣèlérí Párádísè. - Ìṣàkóso rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀. - Ọpẹ́ ni fún Jèhófà Ọba, - Títí ayé laó máa dúpẹ́. - (ÈGBÈ) - Ayé yóò di Párádísè. - Pẹ̀lú ‘gbàgbọ́, ó dájú pé - Ó máa rí bẹ́ẹ̀. Jésù yóò ṣeé, - Torí pó máa ńṣe ìfẹ́ Jáà. 
(Tún wo Mát. 5:5; 6:10; Jòh. 5:28, 29.)