Ayẹyẹ
Ayẹyẹ táwọn Kristẹni máa ń ṣe
Kí ni ayẹyẹ kan ṣoṣo tí Bíbélì sọ pé àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣe?
Àwọn èèyàn Ọlọ́run gbádùn kí wọ́n máa pé jọ láti jọ́sìn Ọlọ́run
Àwọn ayẹyẹ táwa Kristẹni kì í ṣe
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká lọ́wọ́ sí àwọn ayẹyẹ táwọn ẹlẹ́sìn èké dá sílẹ̀?
1Kọ 10:21; 2Kọ 6:14-18; Ef 5:10, 11
Tún wo “Dída Ẹ̀sìn Tòótọ́ Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Èké”
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Ẹk 32:1-10—Jèhófà bínú gan-an sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí pé wọ́n gbìyànjú láti da ẹ̀sìn tòótọ́ pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn èké
Nọ 25:1-9—Jèhófà fìyà jẹ àwọn èèyàn ẹ̀ torí pé wọ́n lọ́wọ́ sí ayẹyẹ àwọn abọ̀rìṣà, wọ́n forí balẹ̀ fún òrìṣà, wọ́n sì tún ṣe ìṣekúṣe
Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Lk 2:1-5—Àkókò tí ìjọba Róòmù pàṣẹ pé kí wọ́n ka àwọn èèyàn ni wọ́n bí Jésù; kò sì jọ pé ìjọba Róòmù lè sọ pé káwọn Júù tó ti di ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí rìnrìn àjò láti lọ ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nígbà òtútù
Lk 2:8, 12—Nígbà tí wọ́n bí Jésù, àwọn olùṣọ́ àgùntàn wà níta, kò sì jọ pé wọ́n lè wà níta gbangba lóṣù December tí òtútù máa ń mú gan-an
Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jẹ 40:20-22—Abọ̀rìṣà ni Fáráò, ó sì pààyàn nígbà tó ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí ẹ̀
Mt 14:6-11—Ọba Hẹ́rọ́dù kórìíra àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi gan-an. Nígbà tó ń ṣe ọjọ́ ìbí ẹ̀, ó pa Jòhánù Arinibọmi
Àwọn ayẹyẹ tó wà nínú Òfin Mósè
Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa tẹ̀ lé Òfin Mósè, títí kan àwọn ayẹyẹ tí wọ́n máa ń ṣe nígbà yẹn?
Tún wo Ga 4:4, 5, 9-11; Heb 8:7-13; 9:1-3, 9, 10, 24
Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa pa òfin Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ mọ́?
Tún wo Ẹk 31:16, 17
Ayẹyẹ orílẹ̀-èdè
Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa lọ́wọ́ sáwọn ayẹyẹ tí ìjọba fi ń rántí àwọn ohun tí wọ́n ti gbé ṣe?
Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa lọ́wọ́ sí ayẹyẹ tí wọ́n fi ń rántí àwọn ogun tí orílẹ̀-èdè ti jà?
Tún wo “Ìjọba—Àwa Kristẹni Kì Í Dá Sí Ogun àti Ọ̀rọ̀ Òṣèlú” àti “Ogun”
Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa lọ́wọ́ sáwọn ayẹyẹ tí wọ́n fi ń júbà àwọn olókìkí èèyàn?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Iṣe 12:21-23—Ọlọ́run fìyà jẹ Ọba Hẹ́rọ́dù Ágírípà Kìíní torí pé kò fi ògo fún Ọlọ́run, àmọ́ ó gbà kí àwọn èèyàn júbà òun
Iṣe 14:11-15—Àpọ́sítélì Bánábà àti Pọ́ọ̀lù kò gbà káwọn èèyàn júbà àwọn
Ifi 22:8, 9—Áńgẹ́lì Jèhófà kan ò gbà kí Jòhánù jọ́sìn òun