Ẹ̀rí Ọkàn
Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé gbogbo èèyàn ni Jèhófà fún ní ẹ̀rí ọkàn?
Tún wo 2Kọ 4:2
Tẹ́nì kan ò bá jáwọ́ nínú ìwà burúkú, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀?
Tẹ́nì kan bá ṣáà ti gbà pé ohun tó dáa lòun ń ṣe, ṣéyẹn náà ti tó?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
2Kr 18:1-3; 19:1, 2—Jèhófà bínú sí Ọba Jèhóṣáfátì torí pé ó ran Áhábù tó jẹ́ ọba búburú lọ́wọ́
Iṣe 22:19, 20; 26:9-11—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé nígbà kan, òun gbà pé ó dáa bóun ṣe ń ṣenúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tóun sì ń fọwọ́ sí i pé kí wọ́n pa wọ́n
Báwo la ṣe lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa kó lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
1Sa 24:2-7—Torí pé ẹ̀rí ọkàn Ọba Dáfídì ń ṣiṣẹ́ dáadáa, kò hùwà àìdáa sí Ọba Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ ẹni àmì òróró Jèhófà
Báwo làwa èèyàn aláìpé ṣe lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ lójú Ọlọ́run?
Ef 1:7; Heb 9:14; 1Pe 3:21; 1Jo 1:7, 9; 2:1, 2
Tún wo Ifi 1:5
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Ais 6:1-8—Jèhófà fi wòlíì Àìsáyà lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ jì í
Ifi 7:9-14—Ẹbọ ìràpadà Jésù ló mú kó ṣeé ṣe fún ogunlọ́gọ̀ èèyàn láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà