Ìmúkúrò Nínú Ìjọ
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn alàgbà máa dáàbò bo ìjọ lọ́wọ́ àwọn tó ń hùwà burúkú?
Báwo ni ìwà burúkú tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan hù ṣe lè kó bá gbogbo ìjọ lápapọ̀?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Joṣ 7:1, 4-14, 20-26—Nígbà tí Ákánì àti ìdílé rẹ̀ hùwà burúkú, gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ló jìyà
Jon 1:1-16—Nígbà tí Jónà ò ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe, ó fi ẹ̀mí gbogbo àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀ sínú ewu
Àwọn ìwà wo ló yẹ kẹ́nì kan sá fún tí kò bá fẹ́ kí wọ́n mú òun kúrò nínú ìjọ Kristẹni?
Kí ló yẹ ká ṣe fún Kristẹni kan tó ń bá a lọ láti máa dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an?
Táwọn alàgbà bá ń gbọ́ ẹjọ́ ẹnì kan tó dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, àwọn ìlànà Bíbélì wo ló yẹ kí wọ́n fi sọ́kàn?
Kí nìdí tó fi máa ń pọn dandan pé kí wọ́n bá àwọn kan wí tàbí mú wọn kúrò nínú ìjọ, báwo nìyẹn sì ṣe máa ṣe ìjọ láǹfààní?
Kí ni Bíbélì sọ nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ?
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí ẹni tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ bá ronú pìwà dà?
Tún wo “Ìrònúpìwàdà”
Kí ni gbogbo wa lè ṣe kí ìjọ lè wà ní mímọ́?
Tún wo Di 13:6-11