ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • scl ojú ìwé 45-47
  • Ìdílé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdílé
  • Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
scl ojú ìwé 45-47

Ìdílé

Jèhófà ló dá ìdílé sílẹ̀

Ef 3:14, 15

Àwọn Òbí

Wo “Àwọn Òbí”

Àwọn Bàbá

Wo “Bàbá”

Àwọn Ìyá

Wo “Ìyá”

Àwọn Ọkọ, Àwọn Aya

Wo “Ìgbéyàwó”

Ọmọkùnrin àti Ọmọbìnrin

Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ máa ṣe?

Le 19:3; Owe 1:8; 6:20; Ef 6:1

Tún wo Owe 4:1

Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ máa ṣègbọràn sáwọn òbí wọn?

Ef 6:1-3; Kol 3:20

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Sm 78:1-8—Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ̀ nípa ohun táwọn baba ńlá wọn ṣe lẹ́yìn tí Jèhófà fún wọn lófin, torí wọ́n fẹ́ káwọn ọmọ náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n sì máa ṣègbọràn sí i

    • Lk 2:51, 52—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ gbogbo ìgbà ló máa ń ṣègbọràn sáwọn òbí ẹ̀ tó jẹ́ aláìpé

Kí ló lè mú kó ṣòro fáwọn ọmọ láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn?

Ro 12:1, 2; 2Ti 3:1, 2, 5

Èrò wo ni Jèhófà ní nípa àwọn ọmọ tí kì í gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu?

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Di 21:18-21—Òfin Mósè sọ pé tí ọmọkùnrin kan bá jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ àti alágídí, tí kì í gbọ́ràn sáwọn òbí rẹ̀ lẹ́nu, ńṣe ni kí wọ́n pa á

    • 2Ọb 2:23, 24—Torí pé àwọn ọmọkùnrin kan tàbùkù sí wòlíì Èlíṣà tó jẹ́ aṣojú Ọlọ́run, abo bíárì méjì pa ọ̀pọ̀ lára wọn

Ojú wo ló yẹ káwọn òbí fi máa wo àǹfààní tí wọ́n ní láti tọ́ ọmọ?

Sm 127:3; 128:3

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Le 26:9—Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá lọ́mọ, wọ́n gbà pé ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà ni

    • Job 42:12, 13—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyà jẹ Jóòbù gan-an, ó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, Jèhófà sì fún òun àti ìyàwó ẹ̀ ní ọmọ mẹ́wàá míì

Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ káwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò máa ṣe síra wọn?

Sm 34:14; Owe 15:23; 19:11

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 27:41; 33:1-11—Jékọ́bù bọ̀wọ̀ fún Ísọ̀ arákùnrin rẹ̀ kí àlááfíà lè wà láàárín wọn, Ísọ̀ náà sì fìfẹ́ hàn sí Jékọ́bù

Àwọn nǹkan wo ló yẹ káwọn ọmọ tó ti dàgbà máa ṣe fáwọn òbí wọn àtàwọn òbí wọn àgbà?

Owe 23:22; 1Ti 5:4

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 11:31, 32—Nígbà tí Ábúráhámù ń kúrò ní Úrì, ó mú Térà bàbá rẹ̀ dání, ó sì ń tọ́jú ẹ̀ títí tó fi kú

    • Mt 15:3-6—Jésù tọ́ka sí ohun tí Òfin Mósè sọ láti fi hàn pé ó yẹ káwọn ọmọ tó ti dàgbà máa tọ́jú àwọn òbí wọn

Àwọn Àna

Wo “Àwọn Àna”

Àwọn Òbí Àgbà

Wo “Àwọn Òbí Àgbà”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́