Ọ̀fọ̀
Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló jẹ́ ká rí i pé kò burú láti ṣọ̀fọ̀ tẹ́nì kan bá kú?
Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé ó máa ń wu Jèhófà láti tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú?
Tá a bá mọ ipò táwọn òkú wà, báwo ló ṣe máa tù wá nínú?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Lk 20:37, 38—Jésù sọ pé ńṣe ló dà bíi pé àwọn tó ti kú wà láàyè lójú Ọlọ́run, èyí sì jẹ́ ká rí i pé ó dájú pé àwọn òkú máa jíǹde
Jo 11:5, 6, 11-14—Lẹ́yìn tí Lásárù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà Jésù kú, ó sọ pé ńṣe ló dà bíi pé Lásárù ń sùn
Heb 2:14, 15—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé kò yẹ ká jẹ́ kí ìbẹ̀rù ikú mú wa lẹ́rú
Kí ló lè mú kí Jèhófà túbọ̀ mọyì ẹnì kan nígbà tó bá kú ju ìgbà tí wọ́n bí i?
Kí ni Bíbélì sọ nípa ikú, kí ni Ọlọ́run sì máa ṣe sí i?
Kí ló mú kó dá wa lójú pé àwọn òkú máa jíǹde?
Ais 26:19; Jo 5:28, 29; Iṣe 24:15
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa èèyàn mẹ́jọ tó kú tí wọ́n sì pa dà jíǹde sáyé, ó tún sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde Jésù sí ọ̀run. Tí èèyàn ẹ bá kú, àwọn àpẹẹrẹ yìí lè tù ẹ́ nínú, wọ́n sì lè fún ẹ nírètí
1Ọb 17:17-24—Wòlíì Èlíjà jí ọmọkùnrin opó kan dìde ní Sáréfátì, tó wà nílùú Sídónì
2Ọb 4:32-37—Wòlíì Èlíṣà jí ọmọkùnrin kan dìde nílùú Ṣúnémù, ó sì fa ọmọ náà lé àwọn òbí ẹ̀ lọ́wọ́
2Ọb 13:20, 21—Nígbà tí òkú ọkùnrin kan fara kan egungun Èlíṣà, ọkùnrin tó ti kú náà jí dìde
Lk 7:11-15—Nígbà tí Jésù wà nílùú Náínì, ó rí àwọn èrò tó fẹ́ lọ sin ọmọkùnrin opó kan, Jésù sì jí ọmọ náà dìde
Lk 8:41, 42, 49-56—Alága sínágọ́gù ni Jáírù, ọmọbìnrin rẹ̀ kú, Jésù sì jí ọmọ náà dìde
Joh 11:38-44—Jésù jí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde, Lásárù sì láǹfààní láti wà pẹ̀lú àwọn arábìnrin rẹ̀, Màtá àti Màríà lẹ́ẹ̀kan sí i
Iṣe 9:36-42—Kristẹni táwọn èèyàn fẹ́ràn ni Dọ́káàsì torí pé ó lawọ́ ó sì tún jẹ́ onínúure. Nígbà tó kú, àpọ́sítélì Pétérù jí i dìde
Iṣe 20:7-12—Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Yútíkọ́sì kú nígbà tó ṣubú láti ojú fèrèsé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì jí ọ̀dọ́kùnrin náà dìde
Nígbà tí Jésù kú, Jèhófà jí i dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò lè kú mọ́, èyí sì mú kó dájú pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ
Jésù lẹni àkọ́kọ́ tí Jèhófà jí dìde sí ọ̀run, tí kò sì ní kú mọ́ láé àmọ́ kì í ṣe òun nìkan ló máa nírú àjíǹde yìí, àwọn ẹni àmì òróró tí iye wọn jẹ́ 144,000 náà máa jíǹde sí ọ̀run