ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • scl ojú ìwé 103-105
  • Kíkó Ohun Ìní Jọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkó Ohun Ìní Jọ
  • Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
scl ojú ìwé 103-105

Kíkó Ohun Ìní Jọ

Ṣé Bíbélì sọ pé ó burú téèyàn bá ní owó àtàwọn nǹkan ìní míì?

Onw 7:12

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Ọb 3:11-14—Torí pé Ọba Sólómọ́nì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, Jèhófà fún un ní ọrọ̀ tó pọ̀ gan-an

    • Job 1:1-3, 8-10—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́rọ̀ ni Jóòbù, ohun tó kà sí pàtàkì jù ni àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé owó àtàwọn nǹkan ìní míì ò lè fúnni láyọ̀ tòótọ́?

Owe 23:4, 5; Onw 2:18, 19; 5:10, 12

Àwọn nǹkan wo ni owó kò lè ṣe?

Sm 49:6, 7, 9, 10; Mt 16:26

Ewu wo ló wà nínú kéèyàn ní owó tàbí ohun ìní tó pọ̀ jù?

Di 6:10-12; Mt 6:24; 1Ti 6:9, 10

Ewu wo ló wà nínú kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀?

Owe 11:4, 18, 28; 18:11; Mt 13:22

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Iṣe 8:18-24—Ìwà òmùgọ̀ Símónì mú kó rò pé òun lè fowó ra àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ Kristẹni

Tá a bá nífẹ̀ẹ́ owó jù, kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa?

Mt 6:19-21; Lk 17:31, 32

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Mk 10:17-23—Ọkùnrin kan ò tẹ̀ lé Jésù torí pé ó nífẹ̀ẹ́ ohun ìní ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ

    • 1Ti 6:17-19—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni tó jẹ́ olówó pé inú Ọlọ́run ò ní dùn sí wọn tí wọ́n bá di agbéraga

Tó bá jẹ́ pé bí ẹnì kan ṣe máa kó ohun ìní jọ ló gbà á lọ́kàn, kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí onítọ̀hún?

Di 8:10-14; Owe 28:20; 1Jo 2:15-17

Tún wo Sm 52:6, 7; Emọ 3:12, 15; 6:4-8

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Job 31:24, 25, 28—Jóòbù mọ̀ pé kò tọ́ kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀, torí ó lè mú kéèyàn fi Jèhófà sílẹ̀

    • Lk 12:15-21—Ká lè mọ̀ pé ó léwu láti máa kó ọrọ̀ jọ, Jésù sọ àpèjúwe ọkùnrin kan tó ní ọrọ̀ àmọ́ tí kò ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run

Kí ló máa jẹ́ káwọn nǹkan tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn?

Owe 30:8, 9; 1Ti 6:6-8; Heb 13:5

Àwọn ìṣúra wo ló ṣe pàtàkì ju ohun ìní tara lọ, kí sì nìdí?

Owe 3:11, 13-18; 10:22; Mt 6:19-21

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Hag 1:3-11—Jèhófà ní kí wòlíì Hágáì sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé ìdí tóun ò fi bù kún wọn mọ́ ni pé ilé tara wọn ni wọ́n ń fi gbogbo àsìkò wọn kọ́, tí wọ́n sì pa ìjọsìn òun tì

    • Ifi 3:14-19—Jésù fún àwọn ará tó wà ní ìjọ Laodíkíà ní ìbáwí tó le torí pé àwọn ohun ìní tara ṣe pàtàkì sí wọn ju ìjọsìn Ọlọ́run lọ

Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ pé Ọlọ́run máa pèsè àwọn nǹkan tá a nílò?

Sm 37:25; Owe 3:9, 10; Mt 6:25-33

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́