ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • scl ojú ìwé 93-94
  • Ìyá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìyá
  • Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
scl ojú ìwé 93-94

Ìyá

Àwọn nǹkan wo ló yẹ kí ìyá máa ṣe?

Owe 31:17, 21, 26, 27; Tit 2:4

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 21:8-12—Nígbà tí Sérà kíyè sí i pé Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì ọmọ òun ṣe yẹ̀yẹ́, Sérà ní kí Ábúráhámù lé Íṣímáẹ́lì lọ kó lè dáàbò bo ọmọ ẹ̀

    • 1Ọb 1:11-21—Nígbà tí Bátí-ṣébà gbọ́ pé Ádóníjà ń gbìyànjú láti fi ara ẹ̀ jọba, Bátí-ṣébà lọ sọ fún Ọba Dáfídì pé kó tètè fi Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ jọba kó lè dáàbò bò ó

Kí nìdí tó fi yẹ káwa ọmọ máa jẹ́ onígbọràn sáwọn ìyá wa, ká sì máa bọlá fún wọn?

Ẹk 20:12; Di 5:16; 27:16; Owe 1:8; 6:20-22; 23:22

Tún wo 1Ti 5:9, 10

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Pe 3:5, 6—Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé torí pé Sérà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ó dà bí ìyá fún àwọn ọmọbìnrin tó pọ̀

    • Owe 31:1, 15, 21, 28—Ìyá Ọba Lémúẹ́lì fún ọmọ rẹ̀ ní ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n nípa ìgbéyàwó, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé ẹni iyì làwọn obìnrin àtàwọn ìyá jẹ́

    • 2Ti 1:5; 3:15—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbóríyìn fún Yùníìsì ìyá Tímótì, torí pé ó kọ́ ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti kékeré, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọkọ rẹ̀ kì í ṣe Kristẹni

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́