ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • scl ojú ìwé 19-21
  • Àwọn Alàgbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Alàgbà
  • Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
scl ojú ìwé 19-21

Àwọn Alàgbà

Àwọn ìlànà wo lẹni tó bá fẹ́ di alàgbà gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé?

1Ti 3:1-7; Tit 1:5-9; Jem 3:17, 18; 1Pe 5:2, 3

Àwọn ọ̀nà míì wo làwọn alàgbà ti gbọ́dọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ rere?

Mt 28:19, 20; Ga 5:22, 23; 6:1; Ef 5:28; 6:4; 1Ti 4:15; 2Ti 1:14; Tit 2:12, 14; Heb 10:24, 25; 1Pe 3:13

Àwọn ìlànà wo lẹni tó bá máa di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé?

1Ti 3:8-10, 12, 13

Tún wo Ga 6:10; 1Ti 4:15; Tit 2:2, 6-8

Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń yan àwọn alàgbà?

Iṣe 20:28

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Iṣe 13:2-5; 14:23—Pọ́ọ̀lù àti Bánábà tí wọ́n jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò yan àwọn ọkùnrin láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ; ohun kan náà làwọn alábòójútó àyíká máa ń ṣe lónìí, wọ́n máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ darí àwọn, wọ́n á sì fara balẹ̀ tẹ̀ lé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa irú ẹni táwọn tó bá fẹ́ di alàgbà gbọ́dọ̀ jẹ́

    • Tit 1:1, 5—Títù máa ń rìnrìn àjò lọ sí àwọn ìjọ lóríṣiríṣi, ó sì máa ń yan àwọn ọkùnrin láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà

Ta ló ni ìjọ, ohun iyebíye wo ni Jèhófà sì fi rà á?

Iṣe 20:28; 1Pe 5:2

Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé ńṣe làwọn alàgbà ń sin àwọn ará, tí wọ́n sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn?

Mt 23:10, 11; Mk 10:42-44; Heb 13:17

Kí nìdí tó fi yẹ káwọn alàgbà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

Flp 1:1; 2:5-8; 1Tẹ 2:6-8; 1Pe 5:1-3, 5, 6

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Iṣe 20:17, 31-38—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ àwọn nǹkan tóun ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà fáwọn alàgbà tó wá láti Éfésù, wọ́n sì fi hàn pé àwọn mọyì gbogbo nǹkan tó ti ṣe

Irú ọwọ́ wo ló yẹ káwọn alàgbà fi mú àwọn ìtọ́ni tó bá wá látọ̀dọ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”?

Mt 24:45, 46; Iṣe 15:2, 6; 16:4, 5; Heb 13:7, 17

Tún wo Iṣe 2:42; 8:14, 15

Ọ̀nà wo ló dáa jù táwọn alàgbà lè máa gbà kọ́ àwọn ará?

1Ti 4:12; 1Pe 5:2, 3

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Ne 5:14-16—Torí pé Gómìnà Nehemáyà bẹ̀rù Jèhófà, kò ṣi agbára ẹ̀ lò lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run, kódà kò gba ohun tó tọ́ sí i

    • Jo 13:12-15—Jésù fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì yẹ káwa náà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀

Báwo làwọn alàgbà ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?

Mt 18:12-14; Jo 17:12; Iṣe 20:17, 18, 35; 1Tẹ 2:7-12

Báwo làwọn alàgbà ṣe lè ran àwọn tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí lọ́wọ́?

Ga 6:1; Jem 5:14, 15

Kí ló yẹ káwọn alàgbà fi sọ́kàn tí wọ́n bá ń kọ́ni?

1Ti 1:3-7; 2Ti 2:16-18; Tit 1:9

Tún wo 2Kọ 11:2-4

Kí nìdí tó fi yẹ káwọn alàgbà rí i dájú pé kò sí àwọn tó ń hùwà àìmọ́ nínú ìjọ?

1Kọ 5:1-5, 12, 13; Jem 3:17; Jud 3, 4; Ifi 2:18, 20

Tún wo 1Ti 5:1, 2, 22

Àwọn wo làwọn alàgbà ń dá lẹ́kọ̀ọ́?

2Ti 2:1, 2

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Mt 10:5-20—Jésù kọ́ àwọn àpọ́sítélì méjìlá bí wọ́n ṣe máa wàásù, lẹ́yìn náà ó rán wọn jáde

    • Lk 10:1-11—Nígbà tí Jésù fẹ́ rán àádọ́rin (70) ọmọ ẹ̀yìn jáde láti lọ wàásù, ó jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan tó yẹ kí wọ́n ṣe àtàwọn nǹkan tí kò yẹ kí wọ́n ṣe

Kí ló máa ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ kí wọ́n lè bójú tó ọ̀pọ̀ ojúṣe tí wọ́n ní?

1Pe 5:1, 7

Tún wo Pr 3:5, 6

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Ọb 3:9-12—Ọba Sólómọ́nì gbàdúrà pé kí Jèhófà fún òun ní ọgbọ́n àti òye, kóun lè ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn Jèhófà

    • 2Kr 19:4-7—Ọba Jèhóṣáfátì yan àwọn onídàájọ́ láwọn ìlú tó wà ní Júdà, ó sì rán wọn létí pé Jèhófà máa wà pẹ̀lú wọn bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà

Báwo ló ṣe yẹ káwọn ará ìjọ máa ṣe sáwọn alàgbà?

1Tẹ 5:12, 13; 1Ti 5:17; Heb 13:7, 17

Tún wo Ef 4:8, 11, 12

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Iṣe 20:37—Àwọn alàgbà ìjọ tó wà ní Éfésù fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù

    • Iṣe 28:14-16—Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń lọ sílùú Róòmù, àwọn ará tó wà nílùú náà rin ìrìn àjò nǹkan bíi kìlómítà márùndínláàádọ́rin (65) kí wọ́n lè wá pàdé ẹ̀ ní Ibi Ọjà Ápíọ́sì, wọ́n sì fún un níṣìírí gan-an

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́