Iṣẹ́ Ìwàásù
Kí nìdí táwọn Kristẹni tòótọ́ fi máa ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn èèyàn?
Ọwọ́ wo ni Jésù fi mú iṣẹ́ ìwàásù?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Lk 4:42-44—Jésù sọ pé torí iṣẹ́ ìwàásù ni Ọlọ́run ṣe rán òun wá sáyé
Jo 4:31-34—Jésù sọ pé ńṣe ni wíwàásù ìhìn rere náà dà bí oúnjẹ fún òun
Ṣé àwọn tó jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ nìkan ni Ọlọ́run sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa wàásù ìhìn rere?
Sm 68:11; 148:12, 13; Iṣe 2:17, 18
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
2Ọb 5:1-4, 13, 14, 17—Ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa wòlíì Jèhófà fún ọ̀gá ẹ̀ tó jẹ́ ìyàwó Náámánì, ará Síríà
Mt 21:15, 16—Nígbà táwọn ọmọkùnrin kan ń yin Jésù torí àwọn nǹkan tó ṣe, àwọn olórí àlùfáà àtàwọn akọ̀wé òfin bẹ̀rẹ̀ sí í bínú, àmọ́ Jésù tọ́ wọn sọ́nà
Báwo làwọn alàgbà ṣe lè ran àwọn ará lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù?
Kí ni Jèhófà àti Jésù ń ṣe fún wa ká lè máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù láṣeyọrí?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Iṣe 16:12, 22-24; 1Tẹ 2:1, 2—Àwọn alátakò fìyà jẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń wàásù, síbẹ̀ Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fìtara bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ
2Kọ 12:7-9—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ‘ẹ̀gún kan nínú ara rẹ̀,’ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àìsàn kan tó ń ṣe é; àmọ́, Pọ́ọ̀lù ṣì ń fìtara bá iṣẹ́ ìwàásù ẹ̀ lọ torí pé Jèhófà fún un lókun
Kí ló mú kó ṣeé ṣe fáwa Kristẹni láti máa wàásù?
Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ káwọn náà lè máa wàásù kí wọ́n sì máa kọ́ni?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Ais 50:4, 5—Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jésù ti kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà kó tó di pé ó wá sáyé
Mt 10:5-7—Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fara balẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nípa bí wọ́n á ṣe máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ
Ojú wo ló yẹ ká fi máa wo iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe?
Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tá a bá ń wàásù?
Kí làwọn nǹkan tá a máa ń sọ fáwọn èèyàn bá a ṣe ń wàásù?
Kí nìdí táwa Kristẹni fi ń tú àṣírí ẹ̀kọ́ èké?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Mk 12:18-27—Jésù lo Ìwé Mímọ́ láti fèròwérò pẹ̀lú àwọn Sadusí kí wọ́n lè mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu bí wọn ò ṣe gbà pé àjíǹde wà
Iṣe 17:16, 17, 29, 30—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá àwọn ará ìlú Àténì fèròwérò, ó ṣàlàyé fún wọn pé ìbọ̀rìṣà ò dáa
Àwọn ọ̀nà wo là ń gbà ṣe iṣẹ́ ìwàásù?
Kí nìdí tá a fi ń wàásù ní gbangba?
Jo 18:20; Iṣe 16:13; 17:17; 18:4
Tún wo Owe 1:20, 21
Tá a bá ń wàásù, kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe sùúrù, ká sì máa lọ léraléra?
Tá ò bá dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àǹfààní wo nìyẹn máa mú wá?
Kí nìdí tó fi yẹ ká múra tán láti wàásù ní gbogbo ìgbà?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jo 4:6, 7, 13, 14—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ Jésù, ó wàásù ìhìn rere fún obìnrin ará Samáríà tó pàdé nídìí kànga
Flp 1:12-14—Nígbà tí wọ́n fi àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n torí ohun tó gbà gbọ́, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè wàásù, ó sì fún àwọn míì lókun
Tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ṣé ó yẹ ká máa retí pé gbogbo èèyàn ló máa gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?
Jo 10:25, 26; 15:18-20; Iṣe 28:23-28
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jer 7:23-26—Jèhófà sọ nípasẹ̀ wòlíì Jeremáyà pé léraléra lòun ń rán àwọn wòlíì sí àwọn èèyàn òun, àmọ́ wọn ò fetí sílẹ̀
Mt 13:10-16—Jésù sọ pé bíi ti ìgbà ayé wòlíì Àìsáyà, ọ̀pọ̀ èèyàn máa gbọ́ ìhìn rere náà àmọ́ wọn ò ní fara mọ́ ọn