ORIN 152
Ilé Tó Máa Mú Ìyìn Wá Bá Ọ
(1 Àwọn Ọba 8:27; 1 Kíróníkà 29:14)
- 1. Jèhófà, ìwọ lo dá ọ̀run, - Síbẹ̀, ọ̀run kò lè gbà ọ́. - Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ilé yìí, - Jọ̀ọ́, jẹ́ kẹ́mìí rẹ wà níbí. - Àwa tí a jẹ́ ènìyàn rẹ - Ti kọ́ ibi ìjọsìn yìí. - Ìjọsìn rẹ ń mú inú wa dùn; - Jọ̀ọ́, tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa. - (ÀSOPỌ̀) - Ìwọ náà lo fún wa - Ní gbogbo ohun tá a ní. - Inú ohun tó o fún wa - La ti ń fún ọ, Bàbá. - (ÈGBÈ) - A dúpẹ́ fún gbogbo ‘hun tó o ṣe, - Jèhófà, à ń kọrin yìn ọ́. - O ti jẹ́ ká lè kọ́ ilé yìí - Tó máa mú ìyìn wá bá ọ. 
- 2. O mọ̀ pé a fẹ́ kọ́ ilé kan - Tó máa mú ìyìn wá bá ọ, - Tó máa ṣèrànwọ́ fẹ́gbẹ́ ará, - Táá sì ran àwọn míì lọ́wọ́. - A ti kọ́ ilé náà tán báyìí. - Iṣẹ́ ṣì pọ̀ gan-an láti ṣe. - Ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣiṣẹ́ tí - Ọmọ rẹ gbé lé wa lọ́wọ́. - (ÀSOPỌ̀) - A fi àkókò wa - Àti ohun ìní wa - Bọlá fún ọ torí pé - Ìwọ nìkan ló yẹ. - (ÈGBÈ) - A dúpẹ́ fún gbogbo ‘hun tó o ṣe, - Jèhófà, à ń kọrin yìn ọ́. - O ti jẹ́ ká lè kọ́ ilé yìí - Tó máa mú ìyìn wá bá ọ.