Awọn Ìṣe Inúrere Ńmú Ìdùnnú Wá
Laipẹ yii ni awọn ontẹwe Ilé-ìṣọ́nà rí lẹta tí ó tẹle e yii gbà: “Ọ̀gbẹ́ni Ọ̀wọ́n:
“Ni oṣu tí ó kọja ní Philadelphia ni a jí àpamọ́wọ́ ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ ọmọbinrin mi lati inu àpò-ìwé alágbèékọ́-ẹ̀hìn rẹ̀. Ni ọsẹ tí ó kọja nipasẹ ifiweranṣẹ, oun ri ẹrù dídì kan gba ninu eyi ti àpamọ́wọ́ rẹ̀ ati iwe aṣẹ-irinna rẹ̀ ati awọn kaadi pataki miiran. Ẹrù dídì naa ni a fi ranṣẹ lati ọwọ́ ẹnikan ti kò fẹ ki a da oun mọ̀, afi pe ẹrù dídì naa ní ẹda itẹjade Ilé-ìṣọ́nà yin kan ninu. Ẹni yoowu kí ó ṣe tí ó gbégbèésẹ̀ ifẹ ará yii (lati inu ilu-nla ifẹ ará) ti ṣe wahala tí ó sì ti náwónara lati dá àpamọ́wọ́ naa pada fun ọdọmọbinrin mi. Idile mi ati emi fi ìmoore kikun han si ẹni onínúrere yii . . . ó jẹ ọna titobi kan lati ‘jẹrii’ paapaa fun awọn ọdọlangba mi (awọn mẹta).”
Kíka Ilé-ìṣọ́nà ti nípalórí igbesi-aye araadọta-ọkẹ lọna tí ó lérè, tí ó sì ńgbìn awọn ànímọ́ aláìlábòsí, inúrere, ati ìgbatẹnirò si wọn ninu. Nisinsinyi iye tí ó ju million méjìlá awọn ẹda itẹjade kọọkan ni a ntẹ ni iye tí ó ju ọgọ́rùn-ún èdè. Iwọ le maa rí iwe-irohin yii gba ninu ile rẹ nipa kikọ ọ̀rọ̀ kun àlàfo ìsàlẹ̀ yii ki o si fi ránṣẹ́ papọ̀ si wa.
Emi yoo fẹ́ isọfunni siwaju sii lori bi emi ṣe le maa gba Ilé-ìṣọ́nà ati Ji! déédéé ní ilé mi. (Kọwe si adirẹsi tí ńbẹ nisalẹ fun isọfunni.)